Nigeria Elections 2019: Aranṣọ, olórin àti àwọn mì í tó maa n fẹ́ kí ìdìbò wáyé ní Nàìjíríà lójoojúmọ́

Aworan okunrin to n ta asia ẹgbẹ PDP
Àkọlé àwòrán Okunnrin yi wa gbiyanju aje nibi ipade apapọ ẹgbẹ PDP ti wọn ti yan oludije sipo Aarẹ ẹgbẹ naa

Asiko eto idibo jẹ asiko to n pa ọpọlọpọ owo wọle fun Naijiria, ti awọn oloṣelu ati ẹgbẹ oṣelu wọn si maa na baba nla owo lati ri i daju pe ẹgbẹ wọn lo bori.

Amọ bi wọn ṣe n na owo wọn, o ni awọn kan to n janfaani gbogbo mudun-mudun gbogbo nkan. Ṣe ti awọn to n tẹwe ni ka sọ ni, tabi awọn ọlọkọ ero to fi mọ awọn janduku.

Oya, ẹ jẹ ka jọ wo awọn ti asiko idibo jẹ asiko yata-yoto fun.

Awọn to n tẹwe

Asiko idibo maa n pese iṣẹ ati owo pupọ fun awọn to n tẹwe.

Nitori pe awọn ni yoo tẹ iwe ipolongo, fila, aṣọ, patako ipolongo, ankara ẹgbẹjọda, ati ṣiṣe ọkọ awọn oloṣelu loge pẹlu iwe ipolongo.

Awọn awakọ

Awọn oloṣelu maa n haya ọkọ lati gbe awọn alatilẹyin wn kaakiri lasiko ipolongo wọn.

Awakọ kan nipinlẹ Eko, Adaba Iyiola sọ fun BBC pe awọn fẹran lati maa ṣiṣẹ fun awọn oloṣelu nitori pe owo maa n wọle daada botilẹ jẹ pe wn maa n gbafẹ ni nibi ipolongo.

O ni ''owo ti wọn maa n san fun wa maa n ju owo to yẹ ki a pa loojọ lọ."

Awọn ọmọ ita

Awọn wọnyii lo n ṣakoso adugbo kọọkan ni awọn ilu nlanla. Wọn si maa n tẹle awọn oloṣelu kaakiri.

Botilẹ jẹ wi pe koko iṣẹ ti wọn n ṣe ko ṣe e sọ, awọn ọmọ ita yi maa n gba owo 'iṣakọlẹ' ki wọn le jẹ ki alaafia o jọba nibi ati lasiko ti awọn oloṣelu ba ti n polongo.

Awọn amuludun

Ipolongo ibo laisi orin ati ijo dabi ounjẹ ti ko ni iyọ.

Awọn olorin ati onijo maa n wa nikalẹ lati da awọn to wa fun ipolongo laraya, ko si ba ọfẹ de o.

Awọn olorin bi i Wasiu Ayinde (K1), Small Doctor, Davido, Saheed Oṣupa, Ọlamide, ati bẹẹbẹ lọ naa ti se e ri.

Awọn miran a tilẹ maa fi orin wọn sọko eebu si awọn ẹgbẹ alatako.

Awọn eleto aabo

Asiko ipolongo jẹ asiko iṣẹ fun awọn eleto aabo naa, nitori wọn maa n wa ni awọn ibudo ipolongo ibo lati ri i pe wahala kankan ko ṣẹlẹ.

Awọn miran tilẹ maa n ṣiṣẹ loru, ṣugbọn wọn maa n gba owo fun pe wọn ṣiṣẹ tayọ akoko to yẹ.

Ajọ INEC maa n ṣeto to yẹ fun awọn naa.

Awọn to n kiri ọja

Asiko iṣẹ ni asiko eto idibo jẹ fun awọn to maa nkiri ọja. Ko si ibi ti ipolongo ibo ti n waye, ti ki i ṣe awọn ni yoo kọkọ de ibẹ.

Bẹrẹ lati ori irẹsi sise, to fi mọ ipanu loriṣiriṣi ati omi tutu. Ọti ati awọn nkan mimu yooku gan kii gbẹyin.

Image copyright Getty Images

Awọn aranṣọ ati awọn to n ta ankara

Plenti politicians dey buy local cloth wey dem dey call ankara dey share am to dia supporters. Ọpọ oloṣelu lo maa n ra awn aṣọ ankara lati pin fun awọn alatilẹyin wọn.

Eyi maa n mu ki awọn to n ta aṣọ ankara ati awọn aranṣọ ta daada.

Awọn agunbanirọ

Lasiko eto idibo, ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, maa n gba awọn ọdọ to n sinru ilu lati ba a ṣiṣẹ.

O si ni eto owo ti wọn maa n san fun awọn agunbanirọ naa. Eyi to tumọ si wi pe awọn ọdọ to ba sinru ilu lasiko eto idibo maa n ri owo yatọ si alawi wọn.

Image copyright Getty Images