Àyájọ́ Rédíò lágbàyéé - Wo ìdí tí Rédíò kò fi leè parun
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

World Radio Day: Àwọn aráàlú ní Rédíò ni àgbára àwọn, òògùn ẹ̀jẹ̀ rúru ni

Ọjọ Kẹtala, osu Keji ọdọọdun ni awujọ agbaye ya sọtọ gẹgẹ bii ayajọ Redio lagbaye.

Idi ree ti BBC Yoruba fi lọ sigboro lati mọ ero awọn araalu nipa ayajọ yii ati pataki rẹ.

Gẹ́gẹ baa ti gbọ, Redio ni ko jẹ ki eti awọn araalu di, nitori bo se n fi iroyin atigbadegba to wọn leti, da wọn lẹkọ, da wọn laraya, to si tun n pa wọn lẹrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ọmọ Naijiria ni, ko si ohun ti o lee rọpo Redio lọdọ awọn, toripe, oogun to lee wo aisan ẹjẹ ruru san ni.

Bakan naa ni wọn gba pe, redio wulo ju mohunmaworan lọ, tori pe o rọrun lati gbe kaakiri, ti owo rẹ ko si ga ju ara lọ.

Wọn ni lasiko idibo, Redio wulo pupọ lati mọ bi eto idibo se n lọ yika orilẹede.