2019 Elections: NCC ní ìròyìn òfégè ni pé ìjọba yóò ti afẹ́fẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ pa lọ́jọ́ ìbò

Anwọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ

Oríṣun àwòrán, @VeridicTech

Ileeṣẹ to n mojuto eto ibanisọrọ ayelujara lorilẹ-ede Naijiria, NCC ti sọ pe, ko si ootọ ninu iroyin kan to n lọ kaakiri pe ijọba apapọ n gbero lati ti oju opo ibanisọrọ GSM gbogbo lorilẹ-ede Naijiria pa.

Iroyin ti ajọ NCC ni ofege ni naa ni ijọba fẹ ṣe eyi lasiko idibo apapọ to n bọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

BBC Yorùbá: Ìbò rẹ ni agbára rẹ, jáde lọ dìbò

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, agbẹnusọ fun ajọ NCC lorilẹ-ede Naijiria, Nnamdi Nwokike ṣalaye pe, iroyin ẹlẹjẹ lasan ni iroyin naa ati pe kii ṣe iroyin to ṣee gbọ seti rara.

Fayoṣe lo fi iroyin naa lede

Ni ọjọ Iṣẹgun ni gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe gbe si ori ikanni twitter rẹ pe, iroyin ti lu si oun lọwọ pe ijọba apapọ yoo sọ agadangodo si ibanisọrọ GSM ati ikanni ayelujara, laarin agogo marun un idaji ọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ idibo aarẹ, di agogo marun un irọlẹ ọjọ Aiku.

Àkọlé fídíò,

Ademọla Ogunbanjo: A nílò bàbá ìsàlẹ̀ nínú òsèlú

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ NCC, Nnamdi Nwokike ni iroyin ofege ni eyi ati pe ko si bi ijọba apapọ ṣe lee maa gbe iru igbesẹ ni iru saa ti oju la de lorilẹ-ede Naijiria bayii.

O ni gẹgẹ bii ajọ to n mojuto ibanisọrọ lorilẹ-ede Naijiria, awọn ko tii gbọ ohun to jọ eyi.

Amọṣa, gbogbo akitiyan lati kan si minisita fun eto iroyin, Lai Mohammed lo ja si pabo lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Àkọlé fídíò,

World Radio Day: Àwọn aráàlú ní Rédíò ni àgbára àwọn, òògùn ẹ̀jẹ̀ rúru ni

Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ dènà lílo ayélujára àti ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lọ́jọ́ ìbò - Fayose

Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose, ti keboosi too sita faraye pe, bi ijọba apapọ ti n yọ so, ni oun naa n yọ gbọ, to si ti de etigbọ̀ oun pe ijọba apapọ ti n dete lati mase jẹ kawọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ alagbeka sisẹ lọjọ idibo.

Gomina ana nipinlẹ Ekiti tun fikun pe, wọn ti se idanrawo ni Ọjọbọ ati ọjọ Ẹti to kọja, lati mọ bi awọn ẹrọ ti wọn fẹ lo fun igbesẹ yii yoo ti sisẹ si, eyi ti wọn ko wa lati orilẹede Israel.

Nigba to n kebosi loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ, Fayose ni lati aago marun un idaji ọjọ Satide ti idibo gomina yoo waye, si aago marun un aarọ ọjọ Aiku ọjọ keji idibo aarẹ, ni ijọba apapọ yoo ti gbohun lẹnu awọn ẹrọ ibaraẹni sọrọ ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe eyi yoo jẹ ko nira fun ẹnikẹni lati pe jade tabi gba ipe lori ẹrọ ibanisọrọ alagbeka rẹ, bẹẹ ni ko nii seese fun awọn ọmọ orilẹede yii lati fi ohunkohun ransẹ si ara wọn lawọn oju opo ikansira ẹni wọn bii Facebook, Twitter, Instagram ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò,

'Wọn ko ni nkan ṣe fún ipinlẹ Ọyọ ni' #BBCGovDebate

Àkọlé fídíò,

Afẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo