BBC Yorùbá ń pàrọwà fún wa lórí ètò ìdìbò
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

BBC Yorùbá: Ìbò rẹ ni agbára rẹ, jáde lọ dìbò

Gẹgẹ bii ileesẹ igbohunsafẹfẹ to pegede, ileesẹ BBC News Yoruba ko gbẹyin nidi riran awọn ọmọ Naijiria leti ojuse wọn nidi eto idibo.

A n rọ awọn araalu lati mase ri eto oselu bii ayo ẹlẹgbin nitori ibo wa ni agbara wa lati yan asaaju ti a fẹ.

A si tun n parọwa sawọn eeyan lati mase ta ibo wọn nitori ohun buruku ni asa ‘Dibo, ko sebẹ’, ko si yẹ ka maa bawọn kopa ninu rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A tun n rọ awọn eeyan wa lati ta kete siwa jagidi jagan nitori ohun buruku ni, ibo la si fẹ ki wọn di, a ko fẹ ki wọn da ilu ru.

BBC News Yoruba wa n kesi yin pe kẹ jade wa dibo, kẹ ran ika atanpako yin nisẹ, nitori ibo wa ni agbara wa.