Madam Sajẹ: Mò ń rọ àwọn akẹẹgbẹ́ mi nínú tíátà láti máṣe kánjú

Alhaja Fausat Balogun, ti gbogbo eeyan mọ si Madam Sajẹ Image copyright Sajetiologa

Ẹ ni ti ọdun ba ba laye, o yẹ ko maa dupẹ nitori aimọye ojo lo ti rọ ti ilẹ ti fi mu.

Idi ree ti Alhaja Fausat Balogun, ti gbogbo eeyan mọ si Madam Sajẹ ninu ere tiata Yoruba, se n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aanu ati aabo rẹ nibayii to pe ẹni ọgọta ọdun loke eepẹ.

Ọjọ Kẹtala osu Keji ọdun 1959 ni wọn bi gbajugbaja osere tiata naa, to si di olokiki ninu isẹ tiata lati ipasẹ ere kan to se lori mohun maworan, eyiti wọn pe akọle rẹ ni Ẹrin Keke lọdun 1990.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Madam Sajẹ si ti kopa ninu awọn ere tiata to le ni ọgọrin.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ayajọ ọjọ ibi rẹ, Alhaja Balogun ni ko si agbẹkẹle mii fun ohun ju Ọlọrunlọ, to si tun n gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun ara rẹ ni ọjọ iwaju.

Image copyright Sajetiologa

Bakan naa lo gba awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu isẹ tiata nimọran pe ki wọn mase kanju lati di ohunkohun laye, amọ ki wọn se suuru de asiko Ọlọrun.

Ẹgbọ ọ̀rọ Madam Sajẹ siwaju-

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSajẹ: Mo n rọ awọn akẹẹgbẹ mi lati se suuru de asiko Ọlọrun

Lara awọn ere ti Madam Sajẹ ti se, eyi to fun ni okiki ninu isẹ tiata ni Nkan Okunkun, Ọmọ Ẹlẹmọsọ, Serekode, Moriyeba, Olowo laye mọ, Ọjọ Ikunlẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ki lo fẹ mọ nipa Madam Sajẹ?

  • Osere tiata ni ọkọ Madam sajẹ, wọn si jọ n sere tiata naa ni. Orukọ rẹ n jẹ Rafiu Balogun
  • Ọkọ Madam Sajẹ jẹ ọga fun iyawo rẹninu isẹ tiata, ki wọn to fẹ ara wọn
  • Inu isẹ tiata ni awọn ọmọ Madam Sajẹ meji wa, ọkan jẹ oludari ere itage, nigbati ekeji jẹ osere obinrin ninu tiata
  • Orukọ ọmọkunrin Sajẹ ni Azeez Balogun, ti orukọ ekeji si n jẹ Bintu Balogun
  • Madam Sajẹ ti gba ọpọ ami ẹyẹ ninu ere sise nilẹ yii ati loke okun
  • Ahesọ ọrọ kan n ja nilẹ pe Madam Sajẹ ti di ọmọlẹyin Kristi nitori aworan kan to ya nibi to ti gbe bibeli lọwọ, sugbọn awọn eeyan kan ni aworan ninu ere tiata ni
  • Madam Sajẹ kii bawọn se ere oloyinbo rara.

BBC Yoruba wa n ki Alhaja Fausat Balogun pe oju yoo maa ri ọdun, Ọlọrun yoo si fun wọn ni ẹmi gigun ati alaafia lati lo iyoku ọjọ aye wọn ninu irọrun.