2019 El;ections: Ìjàmbá iná tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ń kọ àjọ INEC lóminú

Oṣiṣẹ panapana kan n pa ina inu agolo ikẹru si kan. Image copyright Tvc
Àkọlé àwòrán Àmọ́ṣá àjọ náà ní kó sí ìfòyà lórí àṣeyọrí ìdìbò ọdún 2019

Ajọ eleto idibo INEC ti sọ pe, ẹrọ to n yẹ kaadi idibo wo, to din diẹ ni ẹgbẹrun marun lo jona ni ọfiisi ajọ naa to wa nilu Awka nipinlẹ Anambra lọjọ iṣẹgun.

Amọṣa, ajọ INEC ni eyi ko lee pagidina aṣeyọri eto idibo apapọ to n bọ lọna.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade kan eyii ti Amofin Festus Okoye, to jẹ Kọmiṣọna agba feto iroyin ati idanilẹkọ labẹ ajọ Inec fisita fawọn oludibo, o ni ajọ INEC iwadi ti bẹrẹ lori to ohun to fa ijamba ina to jo awọn ohun elo idibo ọhun.

O ni ajọ INEC ti gbe igbesẹ lori kiko awọn kaadi idibo to ku lawọn ipinlẹ miran wa si ipinlẹ Anambra.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Radio Day: Àwọn aráàlú ní Rédíò ni àgbára àwọn, òògùn ẹ̀jẹ̀ rúru ni

"Eyi ni ẹlẹẹkẹta irufẹ iṣẹlẹ ijamba ina yii ti yoo maa waye laaarin ọjọ mejila, lẹyin eyi to waye lawọn ọfiisi ajọ naa ni ijọba ibilẹ Isiala Ngwa nipinlẹ Abia ati Qua'an Pan ni ipinlẹ Plateau.

"A ti fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa ati ileeṣẹ panapana leti, wọn si ti bẹrẹ iwadii lori ohun to sokunfa iṣẹlẹ ijamba ina naa."