2019 Elections: NCC ní ìròyìn òfégè ni pé ìjọba yóò ti afẹ́fẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ pa lọ́jọ́ ìbò

Awọn eeyan kan n wo ninu okunkun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fáyòṣé ló sọ̀ pé ìjọba àpapọ̀ ti parí ètò gbogbo láti dí ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pa pẹ̀lú àwọn irinṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè

Ileeṣẹ to n mojuto eto ibanisọrọ ayelujara lorilẹede Naijiria, NCC ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin kan to n lọ kaakiri pe ijọba apapọ n gbero lati ti oju opo ibanisọrọ GSM gbogbo lorilẹede Naijiria pa lasiko idibo apapọ to n bọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Yorùbá: Ìbò rẹ ni agbára rẹ, jáde lọ dìbò

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, agbẹnusọ fun ajọ NCC lorilẹede Naijiria, Nnamdi Nwokike ṣalaye pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni iroyin naa ati pe kii ṣe iroyin to ṣee gbọ seti rara.

Ni ọjọ iṣẹgun ni gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe kọ ọ si ori ikanni twitter rẹ pe iroyin ti lu si oun lọwọ pe ijọba apapọ yoo sọ agadangodo si ibanisọrọ GSM ati ikanni ayelujara laarin agogo marun idaji ọjọ abamẹta tii ṣe ọjọ idibo aarẹ di agogo marun irọlẹ ọjọ aiku.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ NCC, Nnamdi Nwokike ni iroyin ofege ni eyi ati pe ko si bi ijsba apapọ ṣe lee maa gbe iru igbesẹ ni iru saa ti oju la de lorilẹede Naijiria bayii. O ni gẹgẹ bii ajs to n mojuto ibanisọrọ lorilẹede Naijiria, awọn ko tii gbọ ohun to jọ eyi.

Amọṣa gbogbo akitiyan lati kan si minisita fun eto iroyin, Lai Mohammed lo ja si pabo lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Radio Day: Àwọn aráàlú ní Rédíò ni àgbára àwọn, òògùn ẹ̀jẹ̀ rúru ni