2019 Elections: Bá wo ni ipa àwọn olórí ẹ̀sìn ṣe lágbára tó nínú èsì ìdìbò?

Buhari ati awọn alufaa ijọ Aguda

Oríṣun àwòrán, Premiumtimes

Bi orilẹede Naijiria ṣe jẹ ilu ti awọn eniyan ti mu ọrọ ẹsin ni ọkunkundun, lo fara hàn ninu ọrọ oṣelu.

Ni gbogbo akoko ni awọn oloṣelu maa n beere fun adura, ti awọn adari ẹsin si maa n fi adura da wọn lọla.

Ọpọ igba ni awọn adari ẹsin maa n fi ero ọkan wọn han nipa ẹni ti awọn n ṣe atilẹyin fun, ti wọn si maa n rọ awọn ọmọ ijọ wọn ki wọn tẹle iṣisẹ awọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn igba ọtọtọ ti awọn oloṣelu ti lọ beere fun adura lọdọ awọn asaaju ẹsin rèé:

Aarẹ anaGoodluck Jonathan ati CAN

Oríṣun àwòrán, NAiraland

Bi idibo aarẹ 2015 ṣe n sumọ, ni aarẹ nigba naa, Goodluck Jonathan lọ beere adura lọdọ awọn alufaa labẹ aṣia ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi (CAN).

Ọkan lara ohun to ṣe apẹrẹ bi awọn adari ijọ ṣe ṣe atilẹyin fun ni aworan to wa loke yii, nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ CAN ti n gbadura fun aarẹ ana naa, nigba to ko awọn ikọ Naijiria lọ irinajo lo si ilẹ mimọ, Israel.

Àkọlé fídíò,

BBC Yorùbá: Ìbò rẹ ni agbára rẹ, jáde lọ dìbò

Ọpọlọpọ igba si ni a ri Jonathan ti o lọ ṣe abẹwo si awọn ile ijọsin bi ijọ RCCG lati gba akanṣe adura.

Ẹgbẹ NIFROP ati adura ogoji ọjọ fun Buhari

Ẹgbẹ NIFROP to jẹ akojọpọ awọn adari ẹsin oriṣiriṣi ni oṣu Kọkanla ọdun 2018, pe fun adura ogoji ọjọ, eyi ti wọn pe akori rẹ ni 'Buhari gbọdọ pada wa ni 2019'.

Iru adura wọnyii wọpọ ni gbogbo igba ididbo. Adari ijọ to pe fun adura naa nigba naa, Biṣọọbu Sunday Garuba sọ fun awọn akọroyin ni Plateau, nipinlẹ Jos pe, Ọlọrun ran Aarẹ Muhammadu Buhari lati gba orilẹede Naijiria kuro ninu oko ẹru ni.,

Ti ẹ ba ranti naa, nigba ti Aarẹ Buhari ṣe aarẹ, awọn wolii ati alufa ko ara wọn jọ lati gbadura alaafia fun.

Oríṣun àwòrán, NAiraland

Ni oṣu kọkanla iroyin kan pe Aarẹ ana, Olusegun Obasanjo ti dari ji igbakeji rẹ nigba kan ri, Atiku Abubakar to jẹ oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Aworan to jade lati ibi ipade Obasanjo ati Atiku fi han loju ẹsẹ wipe, awọn adari ijọ bii Biṣọọbu ẹka ijọ Aguda to wa ni Sokoto, Martin Kukah, alfa ijọ musulumi, Ahmed Gumi.

Bakan naa ni olori ijọ Winners Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo wa lara awọn to pari ija laarin awọn mejeeji.

Ọpọ eniyan si lo ti fi ero wọn han wipe, awọn asaaju ẹsin naa n ṣe atilẹyin fun Atiku ki o le di aarẹ.

Oríṣun àwòrán, The News

Ṣugbọn fun awọn ọmọ Naijiria, njẹ iru atilẹyin awọn olori ijọ wọnyii le yi ọkan wọn pada? Oun ti awọn ti a ba sọrọ sọ ree:

Àkọlé àwòrán,

Oladega, Bidemi ati Abayomi

Ẹtọ mi ni lati dibo fun ẹni ti mo fẹ - Oladega

Sọrọsọrọ, Oladega ni, ko si ọna miiran lati mu ilọsiwaju ba orilẹede ti onikaluku ko ba dibo fun ẹni to wu u.

O ni bi awọn oloṣelu ṣe n polongo ni awọn adari ẹsin naa n polongo, ṣugbọn ọmọ Naijiria gbọdọ dibo fun ẹni to wu wọn.

Ko si oun to kan alufaa mi nipa ibo mi - Bidemi Longe

Arabinrin Bidemi Longe sọ fun BBC Yoruba wipe, bo tilẹ jẹ pe onigbagbọ ni oun, oun ko le jẹ ki ero adari ijọ oun sọ ẹni ti oun yoo dibo fun.

O ni bi ero ati ireti alufaa oun ṣe yatọ si ti oun ni ẹni ti ounb yoo dibo fun yoo ṣe yatọ. O ni ẹni ti oun yoo dibo fun, yoo jẹ ẹni ti o ni agbara lati mu irọrun ba awọn ara ilu.

Alufaa to ba fẹ ki n dibo fun oludije oun n tan 'ra rẹ - Abayọmi Ogunremi

Arakunrin Abayọmi Ogunrẹmi ni 'gbadura nṣaamim ko si ija ni ṣọọṣi' ni ọrọ ibaṣepo oun ati adari ijọ oun.

Ninu ọrọ rẹ, o ni alufaa to fẹ ki oun ṣe atilẹyin fun ẹni to oun n ṣe atilẹyin fun n tan ara rẹ jẹ. O ni nitori ki i ṣe gbogbo oun ti alufaa ba fi waasu ni oun maa n tẹle, bẹẹ si ni ọrọ oṣelu naa ri.

O sọ pe, "Alufaa mi ni ero tirẹ, bẹẹ si ni emi naa ni ero temi."