Nigeria Elections 2019: Ènìyàn 15 kú lẹ́yìn tí ìpolongo APC parí ní Port Harcourt

Ileesosan sọ pe eniyan mẹẹdogun lo ku Image copyright Tonye P Cole

Ko din ni eniyan mejila to padanu ẹmi wọn nibi ipolongo ibo ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ṣe nilu Port Harcourt.

Ile iwosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo ti Fasiti ilu Port Harcourt fi idi rẹ mulẹ fun BBC pe, eniyan mẹẹdogun lo ku lasiko ti awọn ero n to kopa nibi eto naa ni papa iṣere Adokiye Amiesimaka n da giiri jade nigba ti ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ APC pari lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila, oṣu Keji ọdun 2019.

Ẹ̀rọ káàdì ìdìbò 4,695 ló jóná lọ́fíìsì INEC ní Anambra

Aranṣọ, olórin àti àwọn mì í ti ko fẹ́ kí ìdìbò kásẹ̀ nílẹ̀ ní Nàìjíríà

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2019: Wo fídíò bí wọ́n ṣe sọ nǹkan lu àwọn adarí APC l'Abẹokuta

Agbẹnusọ fun ileewosan naa, Kem Elebiga sọ pe akọsilẹ ẹka to n mojuto itọju pajawiri ati ijamba ọkọ nileewosan naa fihan pe oku eniyan mẹẹdogun ni wọn gbe wa si ileewosan naa lati papa iṣere ọhun - ọkunrin mẹta, obinrin mejila.

Image copyright Tonye P Cole

Ati wi pe eniyan mejila to farapa ni awọn dokita ṣi n tọju lọwọ, ti awọn mẹta si ti pada sile.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe, bi awọn eniyan ṣe n da giiri jade ninu papa iṣere naa nigba ti eto ipolongo ibo pari, ni wọn bẹrẹ si ni ti ara wọn ṣubu nitori ero to pọ.

Amọ ṣa, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers, sọ pe kọmisana ọlọpaa nipinlẹ naa, Usman Belel ti paṣẹ iwadi ohun to fa titẹra ẹni pa ọhun.

Awọn ibo mii ti awọn eniyan ti ku nibi iwọde oṣelu ni 2019

Lootọ lo da bi ẹni pe ilu Port Harcourt ni awọ̀n eniyan ti padanu ẹmi wọn ju lati igba ti eto ipolongo ibo ọdun 2019 ti bẹrẹ, ṣugbọn iru iṣẹlẹ yii ti waye ni awọn ilu mi i.

Nipinlẹ Borno, awọn eniyan tẹ ara wọn pa, bakan naa ni Taraba, eniyan mẹjọ lo jẹ Ọlọrun nipe.

Bakan naa ni nkan ri nipinlẹ Sokoto lasiko ipolongo ibo. Gbogbo rẹ si waye nibi ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

Fun ẹgbẹ oṣelu PDP, ìtàgé wo lulẹ nibi ipolongo kan ti wọn ṣe ni ipinlẹ Kebbi ko si fijuhan boya ẹnikẹni ku tabi bẹẹkọ.