Atiku ló lè fòpin sébi tó ń pa ọmọ Nàìjírìa- Titi
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

2019 Nigeria Election: Màá gbà f'Ọ́lọ́run tí Atiku kò bá wọlé- Titi

Bi idibo aarẹ orilẹede Naijiria lọjọ Abamẹta ṣe n kan lẹkun, iyawo oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Titi Abubakar sọ pe ọkọ oun, Atiku Abubakar lo to gbangba sun lọyẹ lati fopin si ìṣẹ́ ati osi to n ba ọpọ Naijiria finra.

O ṣalaye nigba ti o ba BBC sọrọ nibi ipolongo ibo ti ọkọ rẹ ṣe nilu Eko wi pe ijọba to wa lode ti kuna lati pese ounjẹ, iṣẹ ati eto aabo fun ara ilu, nitorina asiko ti to fun wọn lati kuro lni iṣakoso.

O fikun ọrọ rẹ pe iriri ti Atiku ni ninu ṣiṣe ijọba ati wi pe erongba rẹ lati fun awọn obinrin ati ọdọ ni anfaani ninu ijọba rẹ wa lara awọn idi ti o fi yẹ ko wọle ibo aarẹ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji ọdun 2019.

Bakan naa, oludigbe fun ipo gomina fẹgbẹ PDP nipinlẹ Eko, Jimi Agbaje ati igbakeji gomina Ipinlẹ Oṣun tẹlẹ ri, Erelu Olusola Obada ni Atiku lo le tun Naijiria ṣe lọwọ yii.

Erelu Obada ti ẹ sọ pe Atiku ko ni ṣai wọle ninu ibo naa.