Atiku ní Afenifere yóò bá lọ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigeria Elections 2019: Afẹ́nifẹ́re ní ọ̀rọ̀ àtúntò làwọn ṣe yan Atiku láàyò

Ọkan lara awọn agbaagba ẹgbẹ Afẹnifere ti salaye fun BBC idi ti awọn yoo fi gbe lẹyin Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo aarẹ orileede Naijiria.

Alagba Ayo Adebanjo ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwọ kan pẹlu BBC pe adisọkan Atiku Abubakar nipa atunto orileede Naijiria lo mu ki awọn yan ni aayo awọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adebanjo ni ṣaaju ki ipolongo idibo to bẹrẹ ni Atiku ti n tẹnumọ ipinnu rẹ lati se eto orileede Naijiria bi ẹya Yoruba ṣe n fẹ.

'Atiku ni irẹjẹ to wa ninu ofin Naijiria lo fa ti a fi nilo atunto. O ni oun yo se ti ofin ti ao ma lo yoo fi rọ wa lọrun'