Nigeria 2019 Elections: Àwọn nọmbà yìí ló le fi bá iléèṣẹ́ ológun sọ̀rọ̀ lásìkò ètò ìdìbò

Awọn number ti oludibo le pe lati ba ileeṣẹ ologun sọrọ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/twitter

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti ṣe ifilọlẹ awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ ti awọn araalu le pe ti wahala ba ṣẹlẹ lagbegbe wọn, ṣaaju, lasiko ati lẹyin eto idibo gbogboogbo ti yoo waye.

Nibi eto naa to waye nilu Abuja, ni Ọga agba ileeṣẹ ologun, Ọgagun Tukur Buratai ti ṣe ifilọlẹ yàrá agbára nibi ti awọn ọmọ ogun yoo ti maa ṣe ọfin toto bi nkan ṣe n lọ kaakiri Naijiria lasiko eto idibo.

Buratai ṣalaye pe awọn rogbodiyan to waye lasiko awọn eto idibo to kọja lorilẹ-ede Naijiria lo mu ki ileesẹ ologun naa tun ero rẹ pa.

Àkọlé fídíò,

Afẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo

Lati yàrá agbára naa ni wọn yoo ti maa mojuto awọn wahala bi jagidijagan lasiko idibo, jiji tabi jija apoti ibo gbe, to fi mọ jiji awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo gbe ati awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu.

Bakan naa, ileeṣẹ ologun yoo mojuto awọn ayederu iroyin to le jade lori ẹrọ ayelujara pẹlu erongba lati da wahala silẹ lasiko eto idibo.

Àkọlé fídíò,

BBC Yorùbá: Ìbò rẹ ni agbára rẹ, jáde lọ dìbò

Lati fi to ileeṣẹ ologun to wa ni agbegbe kọọkan lorilẹede Naijiria leti nipa wahala to ba jẹyọ nibudo idibo rẹ, awọn numba yii ni ko o pe si tabi fi atẹjiṣẹ ṣi, ati fun ẹrọ ayelujara Whatsapp.

07017222225, 09060005290, 08099900131 ati 08077444303.

Bakan naa lo le le pe nọmber pelebe 193 lati ori eikeyi oju opo ibaraẹnisọrọ ti o ba n lo.

Àkọlé fídíò,

Ademọla Ogunbanjo: A nílò bàbá ìsàlẹ̀ nínú òsèlú