Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kàyéfì àti mánigbàgbé tó wáyé lásìkò ìpolongo ìbò

Ija nibi ipolongo ibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oriṣiriṣi iṣẹlẹ apanilẹrin, ipaya ati malegbagbe lo maa n waye nibi ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu, ko si yọ oludije tabi ẹgbẹ oṣelu kankan silẹ.

Bi ipolongo ibo fun eto idibo aarẹ ṣe wa ṣopin loni, ọjọ kẹrinla oṣu Keji, ọdun 2019, a ṣe akojọpọ diẹ lara awọn iṣẹlẹ ti ko ṣe e gbagbe lasiko ti awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe ipolongo ibo wọn.

Aarẹ Muhammadu to n dije fun saa keji gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ṣe awọn 'aṣiṣe manigbagbe kan lasiko ipolongo ibo rẹ.

Nipinlẹ Cross River, Buhari ṣe aṣiṣe lasiko to fẹ ẹ fi oludije fun ipo gomina fun ẹgbẹ APC han nibi ipolongo rẹ. Niṣe ni aarẹ na ọwọ amugbalẹgbẹ rẹ kan to duro ni tosi soke, dipo Owan Enoh to jẹ oludije gan-n-gan.

Omiran to tun waye ni ti ipinlẹ Delta, nibi to yẹ ki Aarẹ Buhari ti gbe asia ẹgbẹ oṣelu APC fun Great Ogboru to jẹ oludije ẹgbẹ naa fun ipo gomina, gẹgẹ bi bi o ṣe maa n waye nibi ipolongo gbogbo.

Àkọlé fídíò,

Obasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

Amọ nigba ti Buhari yoo ṣọrọ, dipo ko sọ pe 'mo gbe asia yii fun oludije wa fun ipo gomina...'', niṣe ni Buhari sọ pe 'mo gbe asia iyi yii fun oludije wa fun ipo aarẹ.''

Lootọ, aṣiwi ko to aṣiṣọ, ọkan lara awọn to duro lori itage pẹlu rẹ ṣe atunṣe loju ẹsẹ, ṣugbọn ọtọ ni nkan ti Buhari sọ. O ni 'fun oludije wa fun ipo sẹnetọ''.

Aṣiṣe ọhun tun waye nigba kẹta.

Àkọlé fídíò,

#BBCNigeria2019: Nnamdi Kanu sọrọ lórí àwọn oludije PDP àti APC

Bakan naa ni aarẹ nigba kan ni Naijiria, Oluṣẹgun Ọbasanjọ yi ohùn pada lori ọrọ igbakeji rẹ nigba to fi jẹ aarẹ, Atiku Abubakar. Atiku ni oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ṣaaju asiko idibo ọdun 2019, Ọbasanjọ sọ pe ti oun ba ṣatilẹyin fun Atiku lati di aarẹ Naijiria, Ọlọrun ko ni dariji oun. Ṣugbọn, iyalẹnu lo jẹ nigba ti Ọbasanjọ yii ọrọ̀ rẹ pada, to si bẹrẹ si ni polongo ibo fun Atiku.

Àkọlé fídíò,

2019 Elections:Bi Ibo rírà ṣe ṣákoba fún iṣẹ ìwé títẹ̀

Iṣẹlẹ miran to le 'panilẹrin', amọ to tun le dunni nitori awọn to farapa ni eyi to waye lọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kini ọdun 2019 nibi ipolongo kan ti ẹgbẹ oṣelu alatako, Peoples Democratic Party, PDP ṣe nipinlẹ Kebbi.

Niṣe ni ìtàgé ti awọn agbaagba ẹgbẹ naa, to fi mọ oludije fun ipo gomina, Isah Muhammad Galaudi, deede wo lulẹ, ti gbogbo awọn to duro sori rẹ si ṣubu.

Fidio 'to ṣafihan iṣẹlẹ naa gbajumọ lori ẹrọ ayelujara, to si jẹ wi pe iha ọtọọtọ ni olukaluku ọmọ Naijiria kọ si i.

Bi awọn kan ṣe sọ pe 'boya awọn to mojuto eto naa ko owo ipolongo ibo jẹ ni ẹni to ṣe ìtàgé naa ṣe ṣe iṣẹ ti ko pojuowo', ni awọn kan sọ pe ere iṣẹ ọwọ awọn oloṣelu naa ni wọn jẹ, nitori wọn lasiko ti wọn n pe orukọ Ọlọrun lati yawọn ya satani, ni ede Larubawa, ni ìtàgé naa wo lulẹ.

Ṣaaju ki ti ipinlẹ Kebbi to o waye, ni iru iṣẹlẹ bẹ ẹ waye ni ilu Maiduguri, nipinlẹ Borno, lasiko ti ẹgbẹ oṣelu APC n ṣe ipolongo ibo aarẹ.

Abala kan lara ibi ti awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa duro si wo lulẹ, ti ọpọ eniyan si farapa. Iroyin ti a ko fidirẹmulẹ tilẹ sọ wi pe ẹnikan padanu ẹmi rẹ nitori ijamba naa.

Ẹwẹ, ojo okuta ni awọn janduku rọ le Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC lori nipinlẹ Ogun, lasiko ti ipolongo ibo aarẹ n lọ lọwọ. Botilẹjẹ wi pe oun naa wa nibi eto naa, ẹgbẹ oṣelu APC fẹsun kan Gomina Ibikunle Amosun pe 'oun lo wa nidi iṣẹlẹ naa.

Ṣaaju asiko naa ni aarin Gomina Amosun ati ẹgbẹ oṣelu APC ko tooro, nitori ẹni ti yoo dije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ naa.

Amosun n ṣe atilẹyin fun Adekunle Akinlade, ṣugbọn ẹgbẹ faramọ Dapọ Abiọdun.

Bo tilẹ jẹ wi pe Akinlade ti darapọ mọ ẹgbẹ Allied Peoples Movement (APM), to si tun jẹ oludije wọn fun ipo gomina, Amosun ṣi n ṣatilẹyin fun. O si tun n sọ pe ti APC l'oun n ṣe ninu idibo aarẹ.

O tilẹ tun mu Akinlade lọ ọ ki Aarẹ Buhari l'Abuja. Lori eyi, ileeṣẹ aarẹ ni ko si nkan to buru ninu ki awọn oludije tabi ẹgbẹ oṣelu lọ ọ ki aarẹ Buhari, eyi ko si ni nkankan se pẹlu atilẹyin rẹ fun gbogbo oludije ẹgbk APC.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) ati Alliance Congress Party of Nigeria (ACPN) naa fi oludije wọn fun ipo aarẹ, Donald Duke ati Oby Ezekwesili silẹ, ti wọn si sọ pe Muhammadu Buhari ni awọ̀n n ṣatilẹyin fun.