JOHESU: L'Oṣogbo, àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn LAUTECHTH wọ́de lórí àìsan owó oṣù

Awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán Awọn alaṣẹ ileewosan nla LAUTECHTH sọ pe awọn ko mọ nipa ẹhonu kankan to ta ko awọn

Awọn oṣiṣẹ ileewosan nla LAUTECH niluu Oṣogbo labẹ aṣia JOHESUti faake kọri pe bi awọn ko ba gba owo oṣu wọn awọn ko ni jade lọ dibo ni ọjọ abamẹta.

Awọn oṣiṣẹ ile ẹkọṣẹ iṣegun naa ṣeleri yii lasiko iwọde ti wọn ṣe ni ọgba ileewosan nla naa nibi ti wọn ti ke sawọn alaṣẹ ileewosan naa lati wa wọrọkọ fi ṣada lori sisan owo oṣu ati ajẹmọnu wọn gbogbo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#BBCNigeria2019: Nnamdi Kanu sọrọ lórí àwọn oludije PDP àti APC

Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ JOHESU nipinlẹ Ọṣun, Morounkeji Adelẹyẹ ṣalaye pe asiko to fun ijọba apapọ lati dẹkun iwa idẹyẹsi awọn oṣiṣẹ yooku nẹka eto ilera

"Lati ọdun 2009 lawọn smọ ẹgbẹ yii ko ti ri ajẹẹlẹ owo oṣu wọn gba titi di asiko yii. Laipẹ yii ni wọn san ajẹẹlẹ owo fawọn dokita iṣegun ti wọn si yọ awọn ọmọ ẹgbẹ JOHESU sẹyin"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFemi Falana: kò yé kí ìdájọ́ òfin yàtó síra wọn ni Naijiria

Wọn ni lara awọn ohun ti wọn n ja fun ni sisan ajẹẹlẹ owo osu wọn, ati agbega awọn oṣiṣẹ to wa ni akasọ kẹrinla iṣẹ ilera siwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo

Amọṣa awọn alaṣẹ ileewosan nla LAUTECHTH ti sọ pe awọn ko mọ nipa ẹhonu awọn oṣiṣẹ tako awọn bikoṣe lati tẹle aṣẹ awọn aṣiwaju ẹgbẹ wọn loke patapata.

Alukoro ileewosan nla LAUTECHTH, Ayọdele Adeyẹmọ ni alaafia ti pada si ileewosan naa lẹyin wakati diẹ tawọn oṣiṣẹ naa fi ṣe ifẹhonu han wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2019 Elections:Bi Ibo rírà ṣe ṣákoba fún iṣẹ ìwé títẹ̀