Ekiti: Ìjọba ti iléeṣẹ́ rẹ́díò Fayose pa nipinlẹ Ekiti

Ileeṣẹ rẹdio Peoples FM
Àkọlé àwòrán Iléeṣẹ́ ààtò ìlú ní iléeṣẹ́ rẹ́díò náà kò gba ìwé àṣẹ ìkọ́lé.

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti gbe ileeṣẹ rẹdio People F.M. to wa ni iluu Ado Ekiti ti pa bayii.

Ileeṣẹ ato ilu nipinlẹ Ekiti gbe ileeṣẹ rẹdio naa ti pa ni owurọ ọjọbọ lori ẹsun pe ko gba iwe aṣẹ ikọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo

Ileeṣẹ rẹdio naa ni wọn ni o jẹ ti gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFemi Falana: kò yé kí ìdájọ́ òfin yàtó síra wọn ni Naijiria

Oludari ẹka ato ilu nipinlẹ Ekiti lo buwọlu Iwe aṣẹ ti wọn fi ti ileeṣẹ rẹdio naa pa.

Gomina Fayose ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#BBCNigeria2019: Nnamdi Kanu sọrọ lórí àwọn oludije PDP àti APC