#BBCNigeria2019: Ààrẹ Buhari ní ìdìbò ọjọ́ Àbámẹ́ta yóò lọ n'ìrọwọ́ rọsẹ̀

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ lori idibo

Aarẹ Muhammadu Buhari ti rọ awọn ọdọ lati maa jẹki awọn oloṣelu lo wọn fun jagidijagan ninu idibo gbogbo ti yoo bẹrẹ pẹlu ibo aarẹ ati ile aṣofin agba lọjọ Abamẹta.

Aarẹ Buhari sọrọ yii nigba to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori ẹrọ amohun-maworan ṣaaju ibo opin ọsẹ yii.

Aarẹ ni awọn oloṣelu le fẹ lo awọn ọdọ lati da rogbodiyan silẹ lasiko ibo nitori wọn ti mọ wi pe awọn ko le wọle.

Àkọlé fídíò,

Femi Falana: kò yé kí ìdájọ́ òfin yàtó síra wọn ni Naijiria

Àkọlé fídíò,

Afẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo

Aarẹ Buhari tun fi da ọmọ Naijiria loju pe idibo ọjọ Abamẹta yoo lọ ni irọwọ rọsẹ, o ni ijọba oun koni faye gba iwa jagidijagan lasiko idibo ati lẹyin eto idibo.

Aarẹ ni ijọba oun yoo gbiyanju lati ri wi pe alaafia jọba lakoko idibo, Aarẹ Buhari ni idi ni yii ti oun fi fọwọ si adehun alaafia pẹlu awọn oludije aarẹ mejilelaadọrin miran l'Ọjọru.

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ lori eto idibo

Aarẹ rọ awọn ọmọ Naijiria lati tu yaya jade lọjọ Abamẹta lati dibo fun ẹni ti wọn fẹ.

Aarẹ Buhari tun parọwa pe ki gbogbo eeyan lepa alaafia lọjọ idibo, ki wọn si yago fun ohunkohun to ba le da eto idibo ọjọ Abamẹta ru.