INEC: Ohùn gbogbo tí wà ní ṣepé fún ìdìbò ní Quan Pan

Aworan awọn oṣiṣẹ Inec Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Awọn oṣiṣẹ Inec n ṣe eto awọn ẹrọ kaadi idibo ati nnkan elo idibo miran

Ajọ eleto idibo orile-ede Naijiria ti kede pe ohun gbogbo ti bọ sipo lati mu ki dibo waye ni ijọba ibilẹ Quan Pan nipinlẹ Plateau.

Ni nnkan bi ọjọ marun un sẹyin ni ina jo awọn nnkan elo idibo ni ileeṣẹ Inec naa to wa ni agbegbe ohun.

Loju opo Twitter Inec ni wọn fi ikede yi si pẹlu aworan ọk ti wọn fi gbe awọn nnkan elo idibo tuntun wa si agbegbe ohun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#BBCNigeriaElections: Ọmọ Ogun iṣẹ́ yá -Adarí àjọ elétò ìdìbò Ogun

Gẹgẹ bi ohun ti wọn salaye ninu ikede naa, gbogbo iwe orukọ awọn oludibo ni ijọba ibilẹ naa ni INEC sọ pe awọn ti tun tẹ pada ti wọn si ti sipo lọ si ọfisi tuntun miran.

Ẹwẹ, ajọ naa tun fi ikede sita l'Ọjọbọ pe awọn ti fi ẹrọ kaadi idibo miran parọ awọn eleyi ti o jona ninu ijamba ina to waye ni ileeṣẹ ajọ naa ni Awka nipinlẹ Anambra.

Wọn ni ẹrọ kaadi idibo fun ijọba ibilẹ mẹrinla lawọn ti pese ti iṣẹ si n lọ lọwọ lati ri wipe awọn ijọba ibilẹ meje to ku naa ri ti wọn gba.

Lẹnu ọjọ mẹta yi,ileeṣẹ INEC mẹta ni ina ti sọ ti ọpọ awọn nnkan elo idibo ti ṣofo.

Iṣẹlẹ yi jẹ ohun to kan ọpọ eeyan lominu pẹlu bi idibo Aarẹ ti ṣe sunmọle.

Lọjọ Abamẹta ni orile-ede Naijiria yoo dibo yan Aarẹ tuntun ati awọn ọmọ ile asofin ti yoo sejọba fun saa ọdun mẹrin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo