Nnamdi Kanu: Kí gan-an ní àwọn nnkan tí Kanu bèrè fún tí ọwọ rẹ tí tẹ?

Aworan Nnamdi Kanu Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán O ti to osu mẹfa ti wọn ti gburo Nnamdi Kanu sẹhin

Ta a ba sọ pe eegun ẹni o jo, ti o si tun jo mọ nkọ?

Ọrọ yi ṣe rẹgi pẹlu olori ikọ to n pe fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, Nnamdi Kanu to ni kawọn ẹya igbo jade dibo lọjọ Abamẹta.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIdibo ko ni waye ti wọn ko ba mu ọkọ mi jade

Ninu ọrọ kan ti o fi sita loju opo Twitter Kanu ni ohun yi ipinnu pada ''nitori ọwọ awọn ti tẹ gbogbo nkan tawọn n beere''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#BBCNigeria2019: Nnamdi Kanu sọrọ lórí àwọn oludije PDP àti APC

Saaju ni Nnamdi Kanu ti kede pe ẹya naa ko gbọdọ kopa ninu idibo lọjọ Abamẹta to jẹ ọjọ ti awọn yoo ṣe eto idibo laarin awọn ẹya Igbo lati mọ boya awọn yoo duro si orile-ede Naijiria tabi ki wọn lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#BBCNigeriaElections: Ọmọ Ogun iṣẹ́ yá -Adarí àjọ elétò ìdìbò Ogun

Ko ti daju ohun gbogbo ti wọn bere fun ti ọwọ wọn tẹ amọ loju opo Twitter niṣe ni awọn eeyan ti n sọ tẹnu wọn nipa iyipada yi.

Emmanuel Nwoke ni tiẹ sọrọ lori bi Kanu ti ṣe yi ipinnu pada ni ọjọ diẹ si idibo ti o si ni ohun n fura si igbesẹ yi

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNnamdi Kanu ti ṣàlàyé bí ó ṣe rìn lẹ́yìn ọdún kan tó dàwátì

Abatta Godfather ati Onyema ni tiwọn n bere pe ki lo de ti Nnamdi Kanu ko ṣe sọ ohun ti wọn bere fun ti ọwọ wọn tẹ?

Iha miran ni ọrọ yi kọ si awọn alatilẹyin Kanumirn ti wọn si ti bẹrẹ si ni sọ ẹgbẹ tawọn yoo dibo fun

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo