NigeriaDecides2019 : Kíni àwọn ohùn tó ṣé kókó tó yẹ ká mọ ṣáájú ìdìbò

Aworan agbalagba kan to n dibo nipinlẹ Ekiti lọdun 2018
Àkọlé àwòrán Ko si ẹni ti ko si aaye fun lati dibo,lopin igba ti o ba ti ni kaadi dibo

Ọjọ a da ti ko ti gbogbo ọmọ Naijiria yoo jade lati dibo yan aarẹ tuntun ti yoo tukọ orileede naa fun ọdun mẹrin.

Jakejado Naijiria ni awọn oludibo ti n jẹ ọrọ idibo yi lẹnu ti ajọ eleto idibo naa ko dawọ iṣe duro nipa eto idibo ohun.

Ẹgbẹ oṣelu mẹtalelaadorin ni yoo dije du ipo Aarẹ ti oludije 1,848 ti 1,615 ninu wọn jẹ okunrin ti obinrin 233 ṣi n du ipo 109 asoju ile asofin agba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí

Fun aaye 360 to wa fun ile asojusofin, awọn oludije 4,635 ni wọn du ipo ohun ti a ri ọkunrin 4,066 to n du ipo naa ti obinrin si jẹ 569 to n gbero lati soju awọn eeyan wọn.

Awọn nnkan wọnyi se pataki lati mọ nipa idibo naa, ni eyi ti a fi ṣe atupalẹ ni ṣoki si isalẹ bayi:

Rii wi pe PVC rẹ wa ni tosi

Ko si ani ani pe ẹni to ba ni PVC lọ́wọ lo le kopa ninu idibo ọla ati ọmiran ti o ba waye lasiko ibo gbogboogbo yii.

Bi o ba mọ ibi ti o fi kaadi idibo rẹ si ri wi pe o wa kalẹ ki o si ma ṣeṣi mu kaadi miran dipo rẹ.

Àkọlé àwòrán Kaadi idanimọ foju jọ kaadi idibo ṣugbọn ko ṣiṣẹ kannaa

Asiko yi kii ṣe igba ti eeyan ma n ya elomiran ni kaadi rẹ,kaadi rẹ ni agbara rẹ, ri wi pe o mojuto daada

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFemi Falana: kò yé kí ìdájọ́ òfin yàtó síra wọn ni Naijiria

Tete kuro nile lọjọ ibo

Gẹgẹ bi ohun gbogbo to ni eto, ajọ INEC fi gbedeke si asiko ti idibo yoo fi waye.

Ti o ba jẹ ẹni ti ko fẹ pẹ pupọ lori ila, yara kuro nile rẹ lasiko ki o ba le dibo lasiko.

Àkọlé àwòrán Awọn oludibo a ma tu yaya lati dibo-yara kuro nile

Ma ṣe gbagbe pe ijọba ti kede eto irinna laarin aago mẹfa si aago mẹfa irọle.Oun ti eyi tunmọ si ni wi pe ko ni si irina ọkọ laarin igba yi nitori naa tete ṣe eto bi o ti ṣe de aaye idibo rẹ lasiko

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Yorùbá: Ìbò rẹ ni agbára rẹ, jáde lọ dìbò

Wọn ko fi aye gba lilo ẹrọ alagbeka ninu aye idibo

Awọn ajọ eleto idibo Inec ti n lọgun ọrọ yi ti pe ṣugbọn a ko ni ye fi to arawa leti.

Bi o ba n bọ wa si ibudo idibo, o le mu foonu rẹ lọwọ ṣugbọn to ba ti wọ inu aaye idibo gangan, ko ni si aaye fun ọ lati lo.

Àkọlé àwòrán Ko si aaye fun lilo ẹrọ ibanisọrọ ninu aaye idibo

Idi ti Inec lawọn lodi si lilo foonu ni ki awọn eeyan ma ba le lo foonu wọn fun ibo rira ati tita.

Ma se wọ aṣọ ẹgbẹ oṣelu tabi ami ẹgbẹ kankan lọ si aye idibo

Gbogbo ipolongo idibo fun ipo Aarẹ ati awọn ile asofin orile-ede Naijiria ti de opin lọjọ kẹrinla, osu keji.

Fun idi eyi ko tọna lati wọ aṣọ ti yoo ma polongo ẹgbẹ kankan.

Àkọlé àwòrán Awọn oṣiṣẹ Inec nibi ti wọn ti n ṣeto idibo Gomina nipinlẹ Ekiti lọdun 2018

Fun aabo tara rẹ naa lọwọ awọn to le fẹ dẹyẹsi ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan tabi omiran,o ṣe pataki ki o ma fun wọn laaye pẹlu pe o wọ aṣọ to jẹ ti ẹgbẹ oṣe

lu kankan.

Jẹun tabi ki o ni etokale de inu rẹ

Okun inu laa fi gbe ti ita.

Toun ti bi o ti ṣe wuwa ki ẹ dibo yin bo ti 'ṣe tọ ati bo ti ṣe yẹ,a ko ni fẹ ki ẹ ma lokun lati kopa ninu idibo naa

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn to n kiri oun mimu ẹlẹrindodo a ma ṣaba wa si aaye idibo

Lọjọ idibo ko ni si lilobibọ ti pupọ ninu awọn olounjẹ ko si ni patẹ.

Fun idi eyi, ri wi pe o jẹun ki o to kuro nile tabi ki o si ṣeto ounjẹ rẹ lọwọ.

A ki baa mọ,ti o ba ri awọn to gbe ounjẹ jijẹ wa si ibi eto idibo naa,ko si ofin to de wi pe ki a jẹun ti ebi ba n pa wa.Ṣaa ti mu owo lọwọ lati ra ounjẹ naa

Ma di owo pupọ wa si aaye idibo

Aaye idibo kii ṣe ibi ti eeyan n di owo pupọ lọwọ lọ.

Fun idi meji la fẹ ki ẹ sọra pẹlu owo pupọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Ẹ́gbẹ̀rún mẹ́rin nàirà ni ẹnikọ̀ọ̀kan ń gbà

Akọkọ ni pe awọn ole le jin owo naa mọ ẹ lara nibi wọduwọdu idibo.

Ẹkeji ni pe awọn agbofinro ni ẹni to ba di owo to ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira lọwọ wa si ibi idibo yoo salaye ti awọn ba ri iru owo bẹ,oun ti o fẹ fi ṣe.

Abọ ọrọ laa sọfun ọmọlouabi, ẹ ri wi pe ẹ tele ofin idibo ki ẹ si yago fun wahala lọjọ ibo.