Nigeria Election 2019: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí

Nigeria Election 2019: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí

BBC n fẹ ki ètò iṣejọba alagbada fẹsẹ mulẹ ni Naijiria BBC Yorùbá ń pàrọwà fún wa lórí ètò ìdìbò.

Gbogbo igbiyanju BBC ni pe ki gbogbo oludibo le jẹ anfani ijọba Tiwantiwa bii tawọn orilẹ-ede agbaye to ku.

Agbara oludibo ni ko jade wa dibo ko tẹ ìka rẹ fun ẹni to wuu.

Gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji Naijiria àti ilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria ni awọn oṣiṣẹ BBC ti kalẹ si.

Nibẹ ni wọn yoo ti maa mu gbogbo nkan to n ṣẹlẹ wa si etigbọ yin laiṣegbe fẹnikan.

Ẹ wa nkan fidile ki ẹ má ṣe kuro loju òpó yii: www.bbc.com/yoruba tabi ki ẹ kan si facebook wa ni: bbcnewsyoruba àti instagram wa ni @bbcnewsyoruba.

Lọsẹ to kọja lo ti yẹ ki idibo sipo aarẹ atawọn aṣofin l'Abuja ti waye ki ajọ eleto idibo INEC to sun un siwaju d Satide, ọjọ Kẹtalelogun. oṣu keji, ọdun 2019.