Nigeria 2019 Elections: Àwọn tí ìdìbò kò dí lọ́wọ́ iṣẹ́

Eba ati ila Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Okun inu la fi n gbé tita

Lasiko ti eto idibo ba n waye ni Naijiria, ki i si lilọ bibọ ọkọ lọjọ idibo.

Bakan naa ni gbogbo ileeṣẹ maa n wa ni titi pa, ayafi awọn kan ti iṣẹ wọn ṣe koko, ti aiṣi ilẹkun wọn le ṣe akoba fun araalu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí

Ileeṣẹ ọlọpaa: Ileeṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bi ọkan gboogi lara awọn ileeṣẹ eto aabo ni Naijiria ti wọn ko le ṣalaikopa ninu eto idibo Naijiria.

Àkọlé àwòrán Eto aabo ṣe pataki lasiko idibo

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ko awọn oṣiṣẹ rẹ si ibudo idibo kọọkan, ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe ileesẹ ọlọpaa kankan ko ni i jẹ titi pa lasiko eto diibo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Yorùbá: Ìbò rẹ ni agbára rẹ, jáde lọ dìbò

Awọn ọmọ ogun: Awọn ọmọ ileeṣẹ ologun naa ko ni i gbẹyin ninu lilọ bibọ lasiko eto idibo gbogboogbo ọdun 2019.

Iṣẹ wọn si ni lati daabo bo gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria. Ati lati dena awọn janduku to le fẹ da wahala silẹ lasiko ti eto idibo ba n lọ lọwọ.

Oṣiṣẹ eto ilera: Bi gbogbo oṣiṣẹ ko ba ti ẹ le jade lasiko idibo, kii ṣe bi ti awọn eleto ilera, nitori pe iṣẹ irapada ẹmi ṣe koko. Nitori naa ẹnikẹni to ba jẹ oṣiṣẹ eto ilera ni anfaani lati lọ si ibi iṣẹ rẹ ti eto idibo ba n lọ lọwọ, ti ẹnikẹni ko si ni i da a duro.

Image copyright Media for Medical
Àkọlé àwòrán Awọn olutọju alaisan

Awọn kan lara awọn eleto ilera yii, lati awọn ileewosan, ati ajọ aladani tilẹ maa n lọ kaakiri ibudo idibo lati pese itọju pajawiri fun ẹnikẹni to ba farapa tabi nilo rẹ lasiko eto idibo.

Oṣiṣẹ ina mọna-mọna ati panapana: Awọn oṣiṣẹ to n mojuto ina mọna-mọna, ati awọn oṣiṣẹ pana-pana naa maa n wa nibi iṣẹ wọn lasiko ti idibo ba n lọ lọwọ, nitori ki wsn le mojuto awọn iṣẹlẹ ijamba ina to ba waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#BBCNigeriaElections: Ọmọ Ogun iṣẹ́ yá -Adarí àjọ elétò ìdìbò Ogun

Awọn akọroyin : Ṣe Yoruba bọ, wọn ni 'eti ọba nile, eti ọba l'oko, eeyan lo n jẹbẹ. Iṣẹ kekere kọ ni awọn ileeṣẹ iroyin n ṣe ṣaaju, lasiko ati lẹyin ti eto idibo ba waye. Awọn akọroyin a si maa lọ kaakiri ibudo idibo lati maa fi bi nkan ṣe n lọ to awọn araalu leti.

Awọn to n ta ounjẹ: Ipa kekere kọ ni awọn to n ta ounjẹ, nkan ipanu loriṣiriṣi, omi ati nkan mimu ẹlẹrin-dodo, nko lasiko eto idibo Naijiria.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olounjẹ ṣe pataki lasiko idibo

Eyi ribẹ nitori pe ọpọlọpọ oludibo ni yoo ti fi ile wọn silẹ lati owurọ kutu lọ si ibudo idibo wọn. Ṣe okun inu lasi fi n gbe titi, eyi ni kii jẹki awọn olounjẹ bi irẹsi, amala, awọn ipanu ti wọn n fi iyẹfun ṣe ati bẹẹbẹ lọ ṣe maa n patẹ si awsn ibudo idibo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFemi Falana: kò yé kí ìdájọ́ òfin yàtó síra wọn ni Naijiria