Nigeria 2019 election: Jàndùkú yìnbọn f'ọ́mọ ọdún mọ́kànlá lẹ́sẹ̀

Nigeria 2019 election: Jàndùkú yìnbọn f'ọ́mọ ọdún mọ́kànlá lẹ́sẹ̀

Kayefi nla ṣẹlẹ nipinlẹ Oṣun lẹyin ti afurasi janduku oloṣelu kan yinbọn fun ọmọdebinrin kan Rukayat Balogun ọmọ ọdun mọkanla nilu Iwara.

Mama ọmọ naa to ba BBC Yoruba sọrọ Fasilat Balogun ṣalaye janduku kan Fọlọrunṣọ Aderibigbe ti orukọ inagijẹ rẹ n jẹ ''Ṣẹrẹrẹ'' lo yinbọn fọmọ oun lẹsẹ.

Balogun ni bi aago mọkanla aabọ alẹ ni ọkunrin ọun wa sile awọn to si yinbọn lẹẹmẹta, o ni oun gan an ni ọkunrin naa wa wa ṣugbọn o ṣe ijamba fọmọ oun nigba ti ko ri oun.