Ọ̀gá ọlọ́pàá pàṣẹ kí wọ́n ṣé ìwádìí ọlọ́pàá inú àwòrán 4+4

Aworan awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @kekeTony

Àkọlé àwòrán,

Ṣadede ni aworan awọn ọlọpaa ti wọn na ika 4+4 yi lu sita loju opo ayelujara

Adele ọga ọlọpaa lorileede Naijiria Mohammed Adamu ti pasẹ ki ẹka to n ṣewadi nnkan aworan bẹrẹ iwaadi lori aworan awọn ọlọpaa mta kan ti wọn jọ bi ẹ ni naka soke lati ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu APC ati Aarẹ Buhari to n du ipo lẹẹkansi.

Loju opo Twitter ileeṣẹ naa ni wọn fi ikede yi si lọjọ Aje.

Gẹgẹ bi ohun ti ikede naa sọ,bi wọn ba ti pari iwaadi na wọn yoo fi abajade rẹ sita fun gbogbo ara ilu.

Àkọlé fídíò,

Àjọ Ọlọ́pàa Naijiria: A ó fi òsìsẹ́ SARS tó se isẹ́ ibi náà jófin

Ohun to ṣe okunfa iwaadi yi ko silẹyin bi arakunrin kan ti ṣe fiwe ranṣẹ si ileeṣẹ ọlọpa loju opo Twitter nipa aitọ iwa ti awọn ọlọpaa to na ika 4+4 naa hu.

Lẹnu ọjọ mẹta yi, awọn ọmọ Naijiria ti n bẹnu atẹ lu ileeṣẹ ọlọpaa fun bi wọn ti ṣe ni wọn n ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu to wa ni ijọba.

Ọrọ naa lagbara pupọ lasiko igba ti ọga ọlọpaa ana ,Ibrahim Kpotun Idris , wa nipo ọga ọlọpaa.

Lasiko rẹ, ọpọ awuyewuye waye laarin awọn oloṣelu paapa awọn ti ile asofin agba to fi mọ awọn ajafẹtọmọniyan kan ti wọn jijọ wọya ija.

Igbesẹ adele ọga ọlọpaa tuntun yi yoo ma ṣe afihan boya nnkan ti yi pada tabi oun naa n ṣe bi ẹni gbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kan.