BBC Yorùbá: Olóòtú ní àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni, ẹ tì rí nkànkan

An osisẹ BBC Yoruba

Ọjọ oni yii lo pe ọdun kan geerege ti ileesẹ iroyin BBC lagbaye sefilọlẹ ileesẹ iroyin BBC lede Yoruba.

Lati ọjọ Kọkandinlogun osu Keji ti ala wọn lori idasilẹ ileesẹ BBC Yoruba si ti di ohun, ọpọ akanse isẹ ni wọn ti gbe seni idi isẹ iroyin agbohunsafẹfẹ nilẹ Naijiria.

Nigba to n salaye bii irinajo ọdun kan yii se lọ, Olootu ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC Yoruba, Temidayọ Ọlọfinsawo ni ọpọ ojo lo ti rọ, ti ilẹ si ti fi mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Nkan ti awọn eeyan nsọ lori BBC Yoruba

Ninu ọrọ rẹ, o ni ọjọ́ rèé bí àná yìí, tí ilé isẹ BBC láàgbáyé, BBC World Service, sàgbékalẹ ilé isẹ ìròyìn BBC News Yorùbá.

Temidayọ ni nígbàtí tí oun kọkọ rí ìkéde ìpòlońgo igbanisisẹ naa, oun ro o lọkan oun wipe, njẹ BBC le da ile ise iroyin Yoruba sile sa?

"Mi o jafara, mo yara fi iwe iwasẹ (CV) mi ranse lori itakun agbaye, mo si n reti esi.

Igbati wọn pemi fun ifọrọwanilẹnuwo, iyalẹnu lo jẹ, nitori mo salabade awọn oyinbo nibẹ. Oyinbo wa gbọ Yoruba bi? Ẹnu ẹ la wa yẹn. Ka ma fa ọrọ gun, mo yege, wọn pemi, mo si bẹrẹ ise."

Àkọlé àwòrán,

A sẹ awa naa lee ni BBC tiwa

Gbogbo wa ti a wọsẹ lọjọ naa yọ mọ ara wa, a mu tíì ati bisikiti. Ahmed Ambali fẹrẹ mu garawa tíì kan, ko to siju lara tíì ọhun.

"Eyi ta n sọ dun, gẹgẹ bi olootu agba ile isẹ BBC News Yoruba, ẹru bami lakọkọ pe, se awọn eniyan maa tẹwọ gba wa, amọ ju bi mo se ro lọ, iroyin wa tan ka orilẹede Naijiria, titi de ọdọ awọn ọmọ Naijiria to wa loke ọkun.

Mo wa ri daju pe , ise gidi ni awọn akẹẹgbẹ mi nibi isẹ n se."

Àkọlé àwòrán,

BBC Yoruba n'iseju kan

"Eyi ta n sọ dun, gẹgẹ bi olootu agba ile isẹ BBC News Yoruba, ẹru bami lakọkọ pe, se awọn eniyan maa tẹwọ gba wa, amọ ju bi mo se ro lọ, iroyin wa tan ka orilẹede Naijiria, titi de ọdọ awọn ọmọ Naijiria to wa loke ọkun.

Mo wa ri daju pe , ise gidi ni awọn akẹẹgbẹ mi nibi isẹ n se."

Olootu BBC Yoruba fikun pe, awọn ọdọ nifẹ si irufẹ iroyin ti awọn ma a n gbejade, wọn kii jẹ ki iroyin awọn dilẹ lori Facebook, ki wọn to salabapin rẹ, eyi to n wu awọn lori.

Àkọlé àwòrán,

Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti jade

"Ohun to dun mọ mi ninu julọ nipa ise naa ni wipe, gbogbo awọn to je osisẹ BBC News Yoruba, ni wọn to gbangba sun lọyẹ. Ifọwọsowọpọ to dan mọran wa laarin wa. Eyi lo n mu ki iroyin ati agbekale awọn itan wa jẹ ara meeriri.

Bakana, ohun to jẹ ipenija fun mi julọ, ni sise adari awọn ti mo n ba sisẹ, awọn to jẹ onmoye, ti wọn ti ni iriri isẹ iroyin kaakiri, sugbọn ti wọn ni ẹmi itẹriba ati ifọkantan gidi ni idi isẹ yii."

O tẹsiwaju pe, "Ko si igbesẹ ti mo gbe ti wọn ki fi yemi pe, 'bo lọmọ ogun, boo lọmọ ogun, wẹyin rẹ wo'. Igbaruku wọn jẹ ohun iyalẹnu, oju ko si ni tiwa.

BBC News Yoruba, asẹsẹ bẹrẹ ni, ẹ o ti ri nkankan nitoripe BBC Yoruba, awa gangan lara."