2019 Elections: Iléeṣé ológun ṣèlérí láti mú àṣẹ Buhari ṣẹ

Oríṣun àwòrán, @HQNigeria
Ileesẹ ologun orilẹede Naijiria ti kede pe, o di dandan ki oun tẹle asẹ ‘ji apoti ibo, ko fi iku se ifa jẹ’, to ba jẹ pe aarẹ Muhammadu Buhari lo pa asẹ naa fun oun.
Lasiko to n fọwọ idaniloju sọya fawọn akọroyin, agbẹnusọ fun ileesẹ ologun, Sagir Musa salaye pe, ẹni to ba ran ni nisẹ laa bẹru, a kii bẹru ẹni ti a jẹ fun.
Musa fikun pe, lootọ ni ileesẹ ologun ilẹ wa yoo fi awọn ọmọ ogun sọwọ fun eto aabo to peye lasiko eto idibo naa, amọ wọn ko ni duro sawọn agọ idibo gangan bikose awọn agbegbe to sun mọ ibẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èyí ni àwọn ìdí tí INEC fi sún ìdìbò aarẹ síwájú
- Ẹnikẹ́ni tó bá ṣáájú láti jì àpótí ìbò, ẹ̀mí rẹ̀ ló fi ń ṣeré - Buhari
- Ihalẹ Buhari: PDP na ìká àbuku sí Buhari lẹyìn ìpàdé wọn
- O ṣeéṣe ki iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá inú àwòrán 4+4
- APC, PDP, CUPP kọ etí ikún sí òfin INEC
- INEC kéde pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú lé tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìpolongo ìbò
"To ba jẹ pe olori orilẹede yii ati alasẹ patapata fun ilẹ Naijiria lo pa asẹ fun wa pe, ka mu ẹyin ẹnikẹni to ba ji ibo balẹ, ẹ jẹ ko da yin loju pe, a mu asẹ naa sẹ laisi tabi sugbọn kankan nipa rẹ.
Àwọn ọmọ Nàíjíríà kan fàbínú yọ lórí ọ̀rọ̀ Buhari
Awọn ọmọ orilẹede yii, ninu eyi ti a ti ri awọn oloselu, ajafẹtọ ẹni, awọn agbẹjọrọ, agbarijọpọ ẹgbẹ oselu ati awọn eekan ilu kan ti foju laifi wo ọrọ to jade lẹnu aarẹ Mohammadu Buhari lasiko ipade ẹgbẹ APC lọjọ Aje.
Bẹẹ ba gbagbe, nibi ipade pajawiri ti aarẹ se pẹlu ẹgbẹ oselu rẹ, APC, lo ti kede pe ẹnikẹni to ba ji apoti ibo gbe lasiko eto idibo to n bọ, yoo fi ẹmi ara rẹ di nitori ijọba ti pasẹ fawọn osisẹ agbofinro lati gbe igbesẹ to yẹ.
Nigba to n fesi lori ọrọ ti aarẹ Buhari sọ yii, alaga ẹgbẹ oselu PDP, Uche Secondus ni o ti foju han bayii pe gbogbo ọna ni Buhari n san lati wa nipo, pẹlu asẹ to pa fun awọn osisẹ ologun ati ọlọpaa naa, eyi ti yoo awọn asaaju APC maa fija jẹ awọn oludibo.
Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Secondus ni ikede Buhari ọhun lo fara pẹ ikede ogun jija lori awọn oludibo ati iwa riru ọkan awọn agbofinro soke si wọn.
Nigba toun naa n fesi lori ikede Buhari yii, ẹgbẹ agbarijọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oselu lorilẹede Naijiria, CUPP, kesi awujọ agbaye lapapọ lati tete di ẹru ẹmi to ba bọ lasiko idibo ru aarẹ Buhari.
Agbẹnusọ fun CUPP, Imo Ugochinyere, to sọrọ lorikọ ẹgbẹ naa ni iwa ikede nita gbangba to tii buru julọ, to si jẹ ikede iwa ika ni Buhari se yii.
Lero ti olori ile asoju sofin nilu Abuja, Yakubu Dogara, lasiko ipade akọroyin to se lori ikede naa ni, o se ni laanu pe eto iselu alagbada wa ti bọ sọwọ olori apasẹ waa.
Nkan ti awọn eeyan nsọ lori BBC Yoruba
Dogara ni o si ya oun lẹnu pe ẹni ti wọn pe ni olori orilẹede kan lee sọ iru ọrọ yii jade, eyi to tako ẹjẹ to jẹ lati daabo bo ẹmi ọm orilẹede yii kọọkan lasiko ibura rẹ.
Ninu ọrọ ti awọn agbarijọpọ awọn ẹgbẹ ajafẹtọẹni, wọn ni ipe Buhari yii tako ofin orilẹede wa,
Aarẹ apapọ fun ẹgbẹ naa, Malachy Ugwummandu ni ọrọ Buhari naa dabi igba to n gba ojuse ẹka eto idajọ se ni, eyi ti ojuse rẹ wa lati maa tumọ iwe ofin orilẹede yii.