Nigeria 2019 Elections: Àwọn aráàlú kan ní ìṣúnsíwájú ìbò ṣàkóbá fún ọrọ̀ ajé

Nigeria 2019 Elections: Àwọn aráàlú kan ní ìṣúnsíwájú ìbò ṣàkóbá fún ọrọ̀ ajé

Lẹyin ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, kede pe oun ti sun ibo aarẹ to yẹ ko waye ni ọjọ Satide, ọjọ Kẹrindinlogun osu Keji ọdun 2019 siwaju, si Satide, ọjọ Kẹtalelogun osu Keji yii kannaa, oniruuru iha ni awọn ọmọ orilẹede yii kọ si ikede naa.

Idi ree ti BBC Yoruba fi jade sita lati mọero awọn araalu nipa isẹlẹ naa atawọn ọna to gba se akoba fun ọrọ aje wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn eeayan kan ni ọpọ onibara awọn ni awọn ti ja kulẹ nitori ibo yii, ti ko si yẹ ki ajọ eleto idibo maa fi tiwọn da awọn araalu duro.

Ẹlomiran ni lati ọdun to kọja ni oun ti fi ọjọ ibo sọkan, tawọn si ti ya sọtọ fun ijọba, ki lo wa de ti wọn tun se yẹ ọjọ yii lati di awọn lọwọ.