Nigeria 2019 Elections: INEC kéde pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú lé tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìpolongo

Mahmood Yakubu, alaga fun ajọ INEC

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ti fi aṣẹ si pe awọn ẹgbẹ oṣelu le tẹsiwaju pẹlu ipolongo ibo wọn, ni imurasilẹ fun eto idibo aarẹ ati tile aṣofin apapọ ti yoo waye lọjọ Abamẹta.

Alẹ ọjọ Aje ni alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu kede asẹ tuntun naa.

Atẹjade kan ti ajọ naa fisita lori Twitter fihan pe, igbesẹ tuntun naa waye lẹyin ti INEC ṣe ipade pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu.

Ṣaaju ni Yakubu kede lọjọ Abamẹta to kọja pe, ko si aaye fun ẹgbẹ oṣelu kankan lati tẹsiwaju ninu ipolongo ibo nitori pe ajọ naa sun idibo siwaju.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Keji lo yẹ ki eto idibo aarẹ ati tile aṣofin o waye, ṣugbọn ajs INEC sun un siwaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọgbọn Yakubu tọka si awọn idi kan, bii eto aabo to mẹhẹ, idiwọ fun pipin eroja idibo ati awọn nkan mi i gẹgẹ bi ohun to fa a ti INEC fi sun idibo siwaju.

Lọgan ti ajọ naa si kede ainile tẹsiwaju pẹlu ipolongo ibo, ni awọn ẹgbẹ oṣelu kan ti n fi ibinu han si igbesẹ ajọ naa.

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Alaye wọn ni pe, to ba ku wakati mẹrinlelogun ki idibo waye, ni ofin Naijiria sọ pe ipolongo gbọdọ pari. Ati pe, INEC gbọdọ faaye gba wọn niwọn igba to ti sun idibo siwaju.

Nibayii, oru Ọjọbọ, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji ni ipolongo ibo aarẹ ati tile aṣofin apapọ yoo wa sopin.