Ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn: Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè ní àṣìta ìbọn ló fa sábàbí

Joseph Attah

Oríṣun àwòrán, Nigeria Customs Service

Àkọlé àwòrán,

Ajọ aṣọbode gba pe lootọ ni oṣiṣẹ wọn to yinbọn pa ọkunrin naa ko tẹ ohun to le dena ki ibọn naa o maa yin ara rẹ.

Ileeṣẹ irinna Iyare Motors to ni ọkọ ti awọn oṣiṣẹ ajọ aṣọbode Naijiria mu, ninu fidio kan to ṣafihan bi wọn ṣe yinbọn mọ arakunrin kan , ti sọ pe, awọn oṣiṣẹ aṣọbode naa ti mu ti yo.

Bo tilẹ jẹ wipe atẹjade kan ti ajọ aṣọbode fi sita sọ pe ''oṣiṣẹ awọn ti wọn lọ yinbọn mọ arakunrin naa, ko ni ọkan lati ṣe bẹ, amọ ibọn to gbe dani lo ṣeeṣi yin ara rẹ.''

Amọ ṣaa, aṣoju ileeṣẹ Iyare Motors to ba BBC sọrọ, Solomon, ṣalaye pe, awakọ wọn jabọ pe awọn oṣiṣẹ aṣọbode ọhun ti mu ọti yo ni owurọ ọjọ Kẹtadinlogun, oṣu Keji ti iṣẹlẹ naa waye.

Eyi lo mu ki wọn maa huwa kebe-kebe, ti wọn si da ọkọ awọn duro lati beere fun owo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn, agbẹnusọ fun ileeṣẹ aṣọbode, Joseph Attah, to ti kọkọ fi atẹjade sita, sọ pe irọ ni ileeṣẹ Iyare Motors n pa.

''Ẹhn ẹhn, àwọn da ẹni to mu ọti yoo mọ? Ibeere ti Attah bi akọroyin wa niyi, bo tilẹ jẹ pe o gba pe lootọ ni oṣiṣẹ aṣọbode to yinbọn pa ọkunrin naa, ko tẹ ohun to le dena ki ibọn naa o maa yin ara rẹ.

Bakan naa lori ẹsun ti ajọ aṣọbode fi kan pe, bọọsi naa ko aṣọ ti ofin ko faaye gba ni awọn oṣiṣẹ awọn ṣe da a duro, Solomon sọ pe:

"Irọ ni, wọn kan n wa ọna lati bo iwa ti wọn hu mọlẹ ni, kiiṣe 'tori pe ọkọ bọọsi wa ko aṣọ ti ofin ko fọwọ si.

Owo ni wọn fẹ ẹ gba lọwọ awọn eniyan wa."

Fidio naa ṣafihan awọn kan to duro, awọn oṣiṣẹ aṣọbọde, ati arakunrin kan ti ara rẹ kun fun ẹjẹ, to si da bi ẹni to ti ku.

Iroyin to gbalẹ kan lẹyin ti fidio naa jade sori ayelujara ni pe, oṣiṣẹ aṣọbode kan lo yinbọn pa ọkunrin naa to jẹ ọkan lara awọn ero ọkọ bọọsi to n rinrinajo ni opopona Ọ̀rẹ̀ si Benin, nitori owo.

Bakan naa ni Attah ko sọ ni pato, ijiya ti yoo wa fun oṣiṣẹ aṣọbode to yinbọn pa ọkunrin naa, tabi boya owo ti wọn fẹ ẹ gba lọwọ awakọ bọọsi naa ni wọn ṣe daa duro.