Nigeria 2019 Elections: Jonathan, Buhari, Obasanjọ sọ̀kò ọ̀rọ̀ lórí làáṣìgbò ìbò

Jonathan, Buhari, Obasanjo

Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe ẹnikẹni to ba ji apoti ibo gbe lasiko eto idibo to n bọ, yoo fi ẹmi ara rẹ di, nitori ijọba ti pasẹ fawọn osisẹ agbofinro lati gbe igbesẹ to yẹ.

BBC Yoruba ti wa wọnu itan lọ lati lọ wu awọn ọrọ to jọra, ti awọn awọn olori Naijiria ti sọ ṣeyin lasiko ibo.

Awọn ọrọ miiran ti awọn aarẹ naa n sọ, si lo n faa bi awọn araalu se n bu ẹnu atẹ lu wọn, ti awọn miiran si n gba oriyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ní ọdun 2015, nigba ti gbogbo Naijiria n mura kirakita fun idibo gbogbogbo ninu eyi ti aarẹ igba naa, Goodluck Jonathan ati Muhammadu Buhari jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC, Jonathan sọ ọrọ kan to mu iwuri ba ọpọlọpọ:

Sugbọn Buhari lo jawe olu bori ninu idibo naa.

Amọ ki ni Buhari gan funra rẹ sọ lori idibo 2015 ti o mu awuyewuye dani nigba naa?

Ẹ o ranti wipe, o ti dije ni ẹẹmẹta ṣaaju 2015 ti o si kuna. Buhari sọ ọrọ yìí ní ọdun mẹ́ta ṣaaju idibo 2015, Oun to sọ rèé:

Àarẹ ana Olusegun Obasanjo, ti o ṣe olori Naijiria laarin ọdun 1999 si 2007 naa ko gbẹyin ninu ọrọ kanka to mu awuyewuye dani.

Ni ọdun 2007 nigba to n ṣe ipolongo ibo fun Umaru Musa Yar'Adua to rọpo rẹ, Ọbasanjọ sọ ọrọ kan ti ọpọlọpọ eniyan bẹnu atẹ lu.

O ni, tiku-tiye ni idibo naa fun ẹgbẹ oselu PDP.