Nigeria 2019 Elections: Alága INEC, Mahmood Yakubu ní àṣẹ Ààrẹ Buhari lórí pípa ẹni tó bá jí ìbò gbé tako ohun tí òfin sọ

Alaga ajọ Inec, Mahmood Yakubu

Alaga ajọ INEC ti tako aarẹ Buhari lori aṣẹ to pa pe ki awọn ologun o maa yinbọn fun ẹnikẹni to ba ji apoti ibo gbe lasiko idibo apapọ to n bọ.

Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ni ofin idibo lorilẹede Naijiria ti la ijiya to yẹ fun ẹnikẹni to ba tapa si ofin idibo nitori naa ajọ INEC ko lee faye gba ofin tabi aṣẹ miran to ba yatọ si ilakalẹ ofin yii.

Ni akoko to fi n ba awọn oniroyin ati alẹnulọrọ lori eto idibo sọrọ nilu Abuja.

Alaga ajọ INEC naa ni ajọ ọhun ko naani ọrọ yoowu ti aarẹ Buhari lee sọ si nitori aṣẹ ati ilana ajọ naa wa lọwọ ajọ naa gẹgẹ bii ajọ to da duro ni ominira.

Àkọlé fídíò,

Nkan ti awọn eeyan nsọ lori BBC Yoruba

Lori iroyin kan tawọn iwe iroyin abẹle kan gbe ni ọjọ iṣẹgun pe awọn agbofinro DSS ti gbe ọkan lara awọn kọmiṣọna rẹ, Ọjọgbọn Yakubu ni pe ko si ootọ ninu iroyin naa.

O ni awọn agbofinro ko wọ ile eyikeyi ninu awọn oṣiẹ rẹ rara.

O wa gbe ilana ti eto idibo ọjọ abamẹta yoo ba jade kalẹ.