Nig-Ghana: Ìjọba àpapọ̀ faraya lórí bí Ghana ṣe lé àwọn ọmọ Naijiria padà sílé

Awọn ọmọ Naijiiria ti wn le wale lati orilẹede Libya

Oríṣun àwòrán, @alessabocchi

Àkọlé àwòrán,

Kii se igba akọkọ ree ti wọn yoo le awọn ọmọ naijiria pada wa sile lati orilẹede miran

Ijọba apapọ ni Naijiria ti fapa janu lori bi ilẹ Ghana se fọwọ osi juwe ile fawọn ọmọ Naijiria to le ni ẹẹdẹgbẹrin laarin ọdun 2018 si 2019.

Asoju ilẹ Naijiria ni Ghana, Ambassador Micheal Abikoye lo sọ eyi di mimọ lasiko to n se ipade pẹlu adari eto irinna ni ilẹ Ghana, Kwame Takyi.

Abikoye ni, iwa ifiyajẹni lọna aitọ ni awọn osisẹ eleto irina ati asọbode ni ilẹ Ghana hu si awọn ọmọ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba ti Asoju Ile Ghana ,Kwame Takyi n fesi, o ni awọn ti wọn le wale naa ni ilẹ Ghana fẹsun kan wi pe, wọn n se asemase bii hihu iwa ole, gbigbe ilu lọna ti ko bofin mu, sise isẹ asẹwo ati lilu awọn eniyan ni jibiti.

Takyi tun fikun pe, ọgọrin ninu awọn ọmọ Naijiria ti wọn le naa n se gbajuẹ ni ilẹ naa ni Osu Kinni ọdun 2019 ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Adari eto irinna ni ilẹ Ghana naa wa parọwa si awọn ara ile Ghana lati ma a wu iwa daradara si awọn ọmọ Naijiria.