Bird Flu: Onímọ̀ ní kò sí òògùn tó leè pa àrùn lùkúlùkú ní Nàíjíríà

Awọn adiẹ ti lukuluku pa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àìsàn lùkúlùkú tí àwọn olóyìnbó ń pè ní bird flu ti pa adìye 3900 ní ìpínlẹ̀ Plateau, lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ ní Bauchi.

Onimọ kan nipa isegun ẹranko ati awọn ohun ọsin abiyẹ ti ni, ko si oogun fun aisan lukuluku (bird flu), lẹyin ti aisan lukuluku pa adiye ẹgbẹrin o din ọgọrun ni ipinlẹ Plateau.

Dokita John Jesuwale lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, wọn ko ti i gba abẹrẹ oogun lukuluku (vaccine) fun aisan lukuluku laaye lorilẹede Naijiria, ati wi pe, ẹnikẹni to ba ko wọle, yoo finmu kata ofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Damilọla Ajayi: Ọ̀dá owó ló ṣún mi dé ìdí lílo ìyarun bíi fèrè

Dokita Jesuwale ni, afẹfẹ ni aisan yii ma n ba rin, ati pe, ti wọn ba si da adiẹ to ni aisan naa papọ mọ adiẹ ti ko ba ni, ewu nla nbẹ fun wọn.

Awọn adiẹ ti lukuluku pa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aisan lukuluku ti awọn oloyinbo n pe ni Bird flu, ti wọn n pẹ ni avian influenza, ma n pa adiyẹ, awon eranko miran ati eniyan pelu. H5N1 ni aisan lukuluku to wọpọ ju.

Dokita onimọ nipa ọsin ẹranko ọhun se alakalẹ awọn ami to ma n jẹyọ lara adiẹ to ba ni aisan lukuluku, eyi taa to sisalẹ yii:

Awọn ami ti ẹ o fi mọ adiẹ to ni aisan lukuluku (bird flu)

  • Oju adiyẹ ati ipin ẹsẹ ori adiyẹ a maa wu.
  • Iyẹ adiyẹ naa a ma a ri wuruwuru
  • Ẹsẹ rẹ a ma a pọn bii igba ti ẹjẹ ba darogun sibẹ.
  • Patako ẹsẹ ti adiyẹ ma fi n lele a wu soke.
  • Ti aisan lukuluku ba mu adiyẹ lati ori, a lọ si ibi ọna ọfun, eleyii ti yoo mu ki ati riran ni wọn lara.
  • Wọn a ma se ikun ni imu, eleyii ti o le jasi iku fun wọn.
  • Igbẹ adiyẹ naa a ma a lẹ mọ oju ara wọn.
  • Wọn ko ni le jẹun daradara.
  • Ẹjẹ ma a wa ni imu ati ẹnu wọn.

Kini ọna abayọ si aisan lukuluku:

Dokita nipa ohun ọsin adie naa, John Jesuwale ni, ki eniyan kọkọ fun awọn adiyẹ ni abẹrẹ ti yoo dẹna aisan lara wọn ati eleyii ti yoo mu wọn ji pepe.

Awọn adiẹ ọsin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Dokita onimọ nipa ohun ọsin naa wa parọwa si awọn to n si adiyẹ lati ri daju wi pe wọn fun wọn loogun lasiko ti yoo dena aarun gbogbo.

Dokita Jesuwale fikun wi pe, adiẹ to ba ti ni aisan naa, pipa ni wọn yoo pa wọn, ko ma baa ran awọn yoo ku.

O fikun wi pe, ijọba gbọdọ dena ki maa ko adiẹ wa si lati apa ariwa orilẹede Naijiria, nibi ti aarun lukuluku ti gbinlẹ, to si ti pa ọgọọrọ adiẹ bayii.

Ninu ọrọ rẹ, o ni ijọba apapọ ma n se iranwọ fun ẹni to ba n sisẹ ohun ọsin, to si padanu ẹran ọsin rẹ.

Dokita onimọ nipa ohun ọsin naa wa parọwa si awọn to n sin adiyẹ, lati ri daju wi pe wọn fun wọn loogun lasiko, eyi ti yoo dena aarun gbogbo lara awọn ohun ọsin naa.