Nigeria 2019 Elections: Ohun mẹ́rin tó jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ Atiku níbi ìpàdé PDP

Atiku Abubakar nibi ipade igbimo alase PDP

Oríṣun àwòrán, NAIRALAND

Lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe ipade igbimọ alaṣẹ rẹ, nibi ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ ọrọ to mu awuyewuye wa pe, ẹnikẹni to ba ji apoti ibo gbe n fẹmi ara rẹ wewu ni.

Ẹgbẹ oṣelu PDP naa ti wa ṣe ipade tirẹ lọjọ Isẹgun, nibi ti gbogbo awọn ogunna-gbongbo ẹgbẹ PDP, to ni ọrọ kan tabi omiran sọ nipa idibo ti wọn sun siwaju ati ọrọ Buhari, ti ri aaye sọ tẹnu wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Damilọla Ajayi: Ọ̀dá owó ló ṣún mi dé ìdí lílo ìyarun bíi fèrè

Awọn ohun meje to jẹyọ ninu ọrọ ti oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oselu PDP, Alhaji Atiku Abubakar naa ree:

  • APC fẹ lo ẹrọ igbalode lati fa isọwọ-sisẹ ẹrọ kaadi idibo sẹyin

Ninu ọrọ rẹ, Alhaji Atiku Abubakar ni ẹgbẹ oṣelu APC ti ran awọn kan lọ sorilẹede China lati lọ kọ iṣẹ, ti wọn si ti ko ẹrọ igbalode le wọn lọwọ.

O ni awọn ẹrọ yii lo le fa ọwọ isẹ awọn ẹrọ kaadi idibo ṣeyin tabi ko sayipada bawọn ẹrọ naa ṣe n ṣiṣẹ pada.

Oludije fun ipo aarẹ naa ni, awọn ẹrọ kaadi idibo ni awọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria, ti awọn alatilẹyin oun pọ si, lo ṣeeṣe ko ma ṣiṣẹ daradara.

  • Oloogun ko ni ipa kankan lati ko ninu eto idibo

Atiku ni o lodi si ofin ijọba tiwan-tiwa lati da awọn oloogun sita nigba idibo.

O ni ko si ofin kankan to ṣe atilẹyin fun lilo awọn ọmọ ogun nigba idibo. Ọrọ yi waye lati tako ọrọ Buhari wipe oun ti paṣẹ fun awọn agbofinro ki wọn fi ọwọ lile mu ẹnikẹni to ba ko awọn janduku wa si ibi idibo.

  • Atiku ni INEC gbọdọ yanju ọrọ ohun elo idibo ko to di Satide

Atiku ti wa ke pe ajọ INEC pe, wọn ko gbọdọ ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan.

O tun sọ fun ajọ naa wipe, ki wọn gbiyanju lati pin gbogbo oun elo idibo laarin akoko yii si ọjọ Satide, ki wọn si ri daju pe awọn ẹgbẹ oṣelu ni anfani lati yẹ awọn ẹrọ naa wo finifini, ki idibo to bẹrẹ ni ọjọ Satide.

  • Atiku pe Buhari ni ‘Ọgagun’ ninu gbogbo ọrọ rẹ

Ninu ọrọ rẹ, 'ọgagun' ni Atiku pe Buhari dipo ti yoo fi pe e ni 'aarẹ'.

O ni ọrọ 'ọgagun' Buhari wipe ki awọn agbofinro fi ọwọ lile mu ẹnikẹni to ba ji apoti idibo, jẹ ọrọ to bani ninu jẹ, ti ko si yẹ ki adari ilu kankan sọ jade lẹnu.