Ìtàn Mánigbàgbé: Mọrèmi Àjàṣorò fi ọmọkùnrin rẹ̀ kanṣoṣo rúbọ fún odò nítorí ìlú

Mọremi Ajasoro

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Ogunwusu, Ojaja 11

Ilu Ile Ifẹ ni orirun ilẹ Yoruba, nibiti ojumọ ti n mọ waye.

Amọ bi Ile Ifẹ se lagbara, to si gbajumọ to yii gẹgẹ bii ilu olokiki, asiko kan wa to la awọn ohun to lagbara kọja ninu itan, ti ilu naa si fẹ parun, gẹgẹ baa ti gbọ.

Akoko yii si ni awọn Igbo ( kii se awọn eeyan to wa lẹkun ariwa orilede Naijiria o) maa n ko awọn eeyan Ile Ifẹ lẹru, to si nira pupọ fun awọn akọni alagbara ọkunrin ni ilu naa, lati gba Ile Ifẹ silẹ lọwọ awọn ọmọ ogun Igbo, to wa n ko wọn lẹru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Niwọn igba to si jẹ pe ko si ohun ti ọkunrin lee se, ti obinrin ko lee se ju bẹẹ lọ, eyi lo mu ki Mọremi fi ara rẹ silẹ lati gba ilu rẹ la lọwọ ikonilẹru.

Gẹgẹ baa se ka itan Mọremi lori itakun agbaye Wikipedia, taa si tun gbọ lẹnu awọn onpitan, ẹwa ti Ọlọrun fun ọmọbinrin naa, to jẹ ayaba, lo lo lati sẹgun fun ilu rẹ.

Mọremi Ajasoro ati ọba, ijoye Ifẹ

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Ogunwusu, Ojaja 11

A si lee ni laisi iranlọwọ Mọremi ni, boya ni ilu ta n pe ni Ile Ifẹ ko ba ti si mọ loni yii, bẹẹ si ni a ko lee sọ itan ilu Ile Ifẹ, ka gbagbe ipa ti Mọremi ko si ilọsiwaju ilu naa.

Awọn ohun to yẹ ko mọ nipa Mọremi Ajaṣoro:

 • Ọmọ bibi ilu Ọffa, lẹba Ilọrin, nipinlẹ Kwara bayii, ni Mọremi, igbeyawo lo si gbe de ilu Ile Ifẹ
 • Ọranmiyan, tii se ọmọ bibi Oduduwa, to tun jẹ Ọba nilu Ile Ifẹ ni ọkọ Mọremi, eyi to mu ki Mọremi jẹ olori abi Ayaba
 • Arẹwa obinrin, akikanju to ni igboya ni Mọremi, to si setan lati fi ohunkohun to ni, gba ilu Ile ifẹ silẹ lọwọ awọn Igbo
 • Idi ree ti Mọremi se tọ odo Ẹ̀sìnmìrìn lọ pe oun yoo fun ni ohunkohun to ba fẹ, niwọn igba to ba fi asiri agbara awọn Igbo naa han oun
 • Mọremi fi ara rẹ silẹ lati jẹki wọn ko oun lẹru, ti ẹwa rẹ si wọ oju Ọba awọn igbo, ẹni to fẹ bii aya, to si di aayo olori rẹ
 • Mọremi farakinra pẹlu awọn Igbo, to si mọ asiri wọn, lẹyin eyi lo yọ pada si Ile Ifẹ lati tu asiri awọn Igbo fun wọn
 • Ọmọ ogun Yoruba bori awọn ọmọ ogun Igbo, ti Mọremi si pada sọdọ ọkọ rẹ tii se Ọba Ọranmiyan lati di ayaba
 • Mọremi fi ọmọkunrin rẹ kansoso, Oluorogbo, rubọ fun odo Ẹsinmirin, nigba ti odo naa beere ọmọ ọhun lọwọ Mọremi, lati fi san ẹjẹ to jẹ fun
 • Oniruuru ibudo awọn obinrin lawọn ileẹkọ fasiti nilẹ wa, bii fasiti Eko ati Ọbafẹmi Awolọwọ, ni wọn fi sọri akikanju obinrin yii
 • Lọdun 2017, Ọba ogunwusi mọ ere kan to ga julọ lorilẹ ede Naijiria, lati fi seranti Mọremi ni aafin Ọọni tile Ifẹ
 • Ọpọlọpọ ere ori itage si ni wọn ti se lati fi se iranti akikanju obinrin naa lede oyinbo ati Yoruba

Ọpọlọpọ itan ni igbesi aye Mọremi Ajasoro kọ wa, to si yẹ ki awa eeyan iwoyi, ati obinrin, ati ọkunrin fi se arikọgbọn.

Mọremi ni ifẹ ilu rẹ lọkan, to si maa n wa igbega ati alaafia rẹ, bakan naa lo y ki awa pẹlu nifẹ iran Yoruba ati orilẹede wa Naijiria lapapọ.

Adagun odo Mọremi ni aafin Ọọni tilu Ile Ifẹ

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Ogunwusu, Ojaja 11

Mọremi ko ri ara rẹ bii obinrin lasan, ti ko lagbara lati se ohunkohun, amọ pẹlu ọgbọn atinuda, lilo ẹwa rẹ lọ to tọ pẹlu igboya, o gba ilu rẹ silẹ lọwọ igbekun.

O yẹ ki awa naa maa ronu, ka si maa gbe awọn igbesẹ lori ohun to lee mu alaafia, idagbasoke ati ominira ba awujọ wa, boya obinrin ni wa, abi ọkunrin, ọmọde ni wa, abi agba.

Mọremi ko jẹ ki ohunkohun jọ oun loju lati fi gba ilu rẹ silẹ lọwọ awọn ọta, bakan naa lo yẹ kawa pẹlu fi ifẹ orilẹede wa siwaju ju ohunkohun lọ, ti a ko si gbọdọ maa ko dukia jọ lati pa orilẹede wa lara.