Nigeria 2019 Elections: Issa Onilu ní APC kò ní fi èrú gba ìbùkún lásìkò ìbò

Nigeria 2019 Elections: Issa Onilu ní APC kò ní fi èrú gba ìbùkún lásìkò ìbò

Agbenusọ fun ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Lanre Issa-Onilu ní, kò sí òótọ́ kankan nínú ẹ̀sùn tí olùdije ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Alhaji Atiku Abubakar fi kan APC.

Atiku Abubakar sọ níbi ìpàdé ìgbimọ̀ aláṣẹ PDP pe, ẹgbẹ oṣelu APC ti lọ kọ àwọn kan níṣẹ́ ní China,lori bí wọ́n ṣe máà jẹ́ kí ẹ̀rọ káádì ìdìbò ṣe ṣégesège lasìkò ìdìbò.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n salaye siwaju lati tako ẹsun naa, Onilu ni awọn isẹ rere ti ẹgbẹ APC ti se sẹyin ni Naijiria ni yoo sisẹ fun, kii se sise magomago ibo lo gbẹkẹle.

O sọ siwaju pe, ẹgbẹ APC ko ni fi eru gba ibukun lasiko ibo to n bọ, ti awn ko si sa kiri l ba awọn orilẹede miran gẹg bi ẹgbẹ oselu PDP ti n se kiri.