Oyo: Abass Bello rọ́pò ọmọ Akala bíi alága káńsù Ogbomọṣọ North

Bello Abass n gba iwe ẹri lọwọ Kọmiṣọna fun ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ọyọ, Bimbọ Kọlade

Oríṣun àwòrán, Insideoyo

Àkọlé àwòrán,

Awuyewuye ti ń wáyé fún ọjọ́ díẹ̀ báyìí lórí bí Ọlamiju Alao-Akala ṣe tẹ̀lé bàbá rẹ̀ lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú ADP

Lẹyin ti wọn yọ Ọlamiju Alao Akala, to jẹ ọmọ gomina ana nipinlẹ Ọyọ kuro nipo gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ ariwa Ogbomoṣọ, iyẹn Ogbomoso Noirth, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣebura fun igbakeji rẹ, Abass Bello Bayewuwọn gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ naa.

Kọmiṣọna fun amojuto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Bimbọ Kọlade lo ṣeto ibura naa nileeṣẹ ijọba ibilẹ Ogbomọṣọ North.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

APC ní Atiku parọ́ lórí ẹ̀sùn pé yóò jẹ́ kí ẹ̀rọ káádì ṣe aṣemáṣe

N ṣe ni awọn agbofinro pọ babi si ayika ileeṣẹ ijọba ibilẹ naa, gẹgẹ bii awọn tisẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ.

Laipẹ yii ni awọn kansilọ mẹrin ninu mẹwa to wa ni ijọba ibilẹ naa, dibo yọ Ọlamiju lẹyin to kede pe oun n fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si ẹgbẹ oṣelu ADP, nibi ti baba rẹ ti n gbe igba dije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò,

Nigeria 2019 Elections: Akala ní APC kò tó bẹ́ẹ̀ láti yọ ọmọ òun nípò alága

Ni owurọ ọjọru ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Adebayọ Alao Akala ṣi n fi to ileeṣẹ BBC news Yoruba leti pe, iwa kotọ ti ko lee duro niwaju ofin ni yiyọ ti wọn yọ ọmọ oun nipo ati pe, oun ṣi ni alaga ijọba ibilẹ Ogbomọṣọ North.