Nigeria 2019 Elections: Ṣé ọwọ́ ti ká Boko Haram ní Nàìjíríà

Awọn oludije lori ọrọ Boko Haram

O ti le ni ọdun mẹwa ti ẹgbẹ agbebọn Boko Haram ti n da wahala silẹ lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari ni adinku ti de ba ọwọja wahala awọn ikọ agbebọn Boko Haram naa, lati igba ti oun ti de ori oye ni ọdun 2015.

Awọn alatako rẹ si ti koju rẹ pe, eyi jinna si ootọ nitori, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ọwọja awọn agbebọn naa tun ti gberu sii.

Ṣaaju idibo orilẹede Naijiria ni ọjọ Kẹrindinlogun loṣu Keji, ikọ ayẹwo oluwadi fun ileesẹ BBC, (BBC reality Check) gbe awọn ohun tawọn eeyan n sọ lori bi eto abo ṣe ri lorilẹede Naijiria.

Kini Boko Haram?

Ni ọdun 2002 ni wọn da ẹgbẹ Boko Haram silẹ, gẹgẹ bii ẹgbẹ ti kii se oniwahala pẹlu afojusun ati ṣe afọmọ ilana ẹsin Islam lẹkun ariwa orilẹede Naijiria.

Amọṣa ẹgbẹ naa yi pada di agbebọn ninu ilepa awọn afojusun rẹ.

Kii ṣe orilẹede Naijiria nikan ni Boko Haram wa mọ bayii, itakun rẹ ti kan de awọn orilẹede to fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Naijiria bii Chad, Niger ati Cameroun.

Ọkẹ aimoye awọn eeyan ni wọn ti ran lọ sọrun apapandodo, ti awọn bi miliọnu meji miran si ti di atipo.

Boko Haram kii ye ji awọn akẹkọ gbe eleyi to mu ki oju orilẹede agbaye ṣi si ọdọ rẹ lọdun 2014, lẹyin to ji nnkan bii ọọdunrun akẹkọbinrin gbe nileewe kan to wa ni ilu Chibok nipinlẹ Borno, ipinlẹ ti Boko Haram ti kọkọ di agbebọn.

Ni ọdun 2015, Boko Haram gba idanimọ gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunmọmi to buru julọ lagbaye, gẹgẹ bi ajọ to wa fun ọrọ aje ati alaafia lagbaye ṣe sọ.

Lati igba yi wa ni awọn agbegbe ti ẹgbẹ agbebọn naa gba ti dinku, bi o tilẹ jẹ wi pe o ṣi n ṣọṣẹ lẹkun naa.

Awọn ohun ti wọn n sọ

Aarẹ tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ to n ṣatilẹyin fun oludije ẹgbẹ alatako, Atiku Abubakar, ti bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Buhari lori igbesẹ gbigbogun ti Boko Haram.

"Eto abo ti dẹnukọlẹ gidigidi, ijinigbe si wa kaakiri" ni ọrọ ti Ọbasanjọ sọ ni oṣu kinni.

Amọ Buhari ni eto abo ti yatọ. O ni wọn ti "wagbo dẹkun" si wọn lati ọdun 2015 ni ipinlẹ Borno.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

O le ni ẹgbẹrun meji eeyan to ti di atipo nitori Boko Haram

Ṣe ikọlu Boko Haram ti dinku?

Aisi abo to peye ati ibanisọrọ to ye kooro n mu ko nira fun ijọba atawsn ajs aladani gbogbo lati ṣe ayẹwo to tọ.

Ajọ aṣeṣiro orilẹede Naijiria, NBS lo n pese awọn iroyin iwadi nipa ọrọ aje, ọrọ ilu ati abo kaakiri Naijiria, ṣugbọn agbẹnusọ wọn kan ṣalaye fun BBC pe, awọn ko ni iroyin to kuna lori iṣẹ Boko Haram.

Amọṣa, iwadii ti ajọ Armed Conflict Location & Event Data Project (ACLED) ṣe, ayẹwo awọn iroyin to n jade ninu awọn ileeṣẹ iroyin abẹle atawọn iroyin miran.

Lati nnkan bii ẹgbẹrun marun eeyan lọdun 2015, iye awọn eeyan to ku nipasẹ ikọlu Boko Haram ti wa silẹ si bii ẹgbẹrun kan laarin ọdun mẹta sẹyin.

Eyi waye lẹyin tawọn ologun kọju oro si Boko Haram ni ọdun 2015, pẹlu atilẹyin awọn orilẹede agbaye ti wọn si gba awọn ilu ti o wa labẹ iṣakoso iks agbebọn naa pada.

Nitori naa, ootọ ni Aarẹ Buhari sọ pe, ipaniyan awọn agbebọn naa ti ls silẹ gidigidi lati igba ti o ti de ipo ni ọdun 2015, amọṣa o tun ti peleke sii ni ọdun 2019.

"Bi ọrọ ṣe ri bayii buru pupọ ni iwoye temi. O si jina si pe wọn ti bori ikọ naa." Ni ọrọ Alex Thurston to jẹ ajọgbọn ims nipa oṣelu ati ọrọ ẹsin ni fasiti Miami ni Ohio.

Ifipajinigbe nkọ?

Ilana ayẹwo ti ajọ ajọṣepọ ilẹ okeere, CFR, to wa ni ilu Washington lo n gbe awọn iroyin ijinigbe lawọn iroyin abẹle yẹwo eleyi to fihan pe laaarin ọdun 2014 si 2015 ti agbara Boko Haram le kenka julọ ni iṣẹlẹ ijinigbe pọ julọ.

Amọṣa, pẹlu adinku to de ba ijinigbe ni ọdun 2016, o tun ti gbe ẹnu soke bayii paapaa pẹlu iṣẹlẹ ọọdunrun o le mẹwa to waye ni ọdun to kọja.

Nitori naa nigba ti Aarẹ tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ sọ pe " eto abo ti dẹnu kọlẹ pẹlu ijinigbe ni ibi gbogbo" oots ọrs lo sọ nitori pe ijigbe tun ti burẹkẹ sii, ni pataki julọ pẹlu bi wọn ṣe ji awọn akẹkọbinrin to le ni ọgọrun gbe ni Dapchi ni ọdun 2018.

Ohun ti o n ba spọ lẹru ni bi awọn agbebọn Boko Haram ṣe n lo awọn smọde gẹgẹ bi irinsẹ iku pẹlu ado oloro. Ni ọdun 2017 ati 2018, iṣẹlẹ ikọlu ado oloro bi mẹtadinlọgọrin ati mẹrindinlọgbọn ni ṣiṣẹ n tẹle nipasẹ awọn ọmọde lo waye. Ni ọdun 2016 mẹsan lo waye gẹgẹ bii ajọ UNICEF ṣe sọ.

Ṣe ibi gbogbo ni ijinigbe ti n waye?

Agbeyẹwo bi iṣẹlẹ yii ṣe n waye kaakiri Naijiria, eyi ko ri bẹẹ pẹlu bi o ṣe jẹ pe iha ila oorun ariwa orilẹede Naijiria ni wọn ti n ṣọṣẹ.

Bakan naa ni ijinigbe n waye ni ẹkun aringbungbun gusu orilẹede Naijiria nibi ti iwapo rọbi ti n waye-eyi ko ni ohunkohun n ṣe pẹlu Boko Haram.