Nigeria 2019 Elections: Tinubu ní òun yóò sàjọyọ̀ ìsẹ́gun lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀

Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, @AsiwajuTinubu

Eekan kan ninu ẹgbẹ oselu APC, Bola Ahmed Tinubu ti woye pe jinnijinni ti n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP, ti wọn si ti n sa kijokijo kiri.

Tinubu ni niwọn igba ti ara awọn ọmọ ẹgbẹ oselu alatako naa ko balẹ mọ, o yẹ kawọn ọdọ ninu ẹgbẹ APC bẹrẹ si ni se koriya lati ri daju pe wọn tẹnpẹlẹ mọ eto koriya ti wọn n se fawọn ọdọ lati dibo.

Oloye Tinubu kede ọrọ yii lasiko to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ nilu Eko lọjọru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni asiwaju ninu ẹgbẹ APC ọhun fikun pe o yẹ kawọn ẹya Igbo dibo fun ẹgbẹ APC nitori ko si igba kankan ti ijọba APC fọwọ rọ wọn sẹyin tabi dẹyẹ si wọn ninu pinpin ere ijọba tiwantiwa.

Àkọlé fídíò,

Àyájọ́ èdè abínibí: Onímọ̀ ní èdè Yorùbá kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, ó rẹwà

Tinubu tun rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ ẹgbẹ APC lati ko awọn ọmọ ẹgbẹ PDPto n ya wa sinu ẹgbẹ oselu ọhun mọra nitori gbogbo wọn ni wọn ti di ojulowo ọmọ ẹgbẹ.

Ẹyin ọdọ, ẹ yago fun jiji apoti idibo - Tinubu

Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu ti paroko ikilọ ranṣẹ sawọn ọdọ nipinlẹ Eko pe ki wọn yago fun jiji apoti idibo gbe lasiko idibo aarẹ ati ile aṣofin apapọ to n bọ lọjọ abamẹta.

Otinubu ni " Ẹ ti gbọ ohun ti Buhari sọ nipa jiji apoti ibo gbe. Mi o ran ẹnikẹni lati lọ ji apoti ibo gbe o. Kaadi idibo mi lemi fi n ja nitemi o.bi ẹ ba ji apoti ibo gbe tabi da wahala silẹ tọwọ ba ba yin, mi o lọwọ ninu iyẹn o."

O ni awọn ti tẹwọ gba isunsiwaju idibo naa latọwọ ajs INEC nitori ọdọ ajọ INEC ni ofin fi si lori irufẹ iṣẹlẹ ba waye.

Àkọlé fídíò,

Aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bọla Tinubu kìlọ̀ fáwọn ọ̀dọ́ lórí jíjí àpótí ìbò gbé

"Iro opolopo awon oniroyin po. Eleyi ti mi o so l'ose to koja, won ni mo so, a so niyen". Olori egbe APC Bola Tinubu ro awon omo egbe pe ki won jade dibo fun Aare Muhammadu Buhari ni idibo ojo Satide.

Ninu oro re, o so pe PDP ni awon ba ja. Pe awon o ba ajo INEC ja nitori pe ofin wa leyin won ati pe o sese ki won ni ipenija ni won fi sun idibo naa siwaju. O gba l'adura pe ajo INEC yoo so layo lori idibo yii ti APC yoo si jawe olubori. O benu ate lu egbe PDP wipe won lo d'ogbon lo fina bo'le l'Abia, won pale oko mo ati bee bee lo. O fi orin ayajo Sunny Ade kan ba won wi pelu ijo lese.O gba awon omo egbe n'iyanju pe ki won ma ba enikankan ja. O ni ki won gba awon omo PDP ti won darapo mo egbe APC wole.