Àwọn òbí ló fa akùdé tó ń bá èdè abínibí - Olùkọ́
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àyájọ́ èdè abínibí: Onímọ̀ ní èdè Yorùbá kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, ó rẹwà

Lónìí tíí ṣe ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kejì ọdún 2019, ni àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé yà sọ́tọ̀ fún àgbélárúgẹ èdè abíníbí lágbàáyé.

Ìdí rèé tí BBC Yorùbá fi bọ́ sígboro láti mọ ipò tí èdè Yorùbá wa, ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ láti máa gbọ́ lẹ́nu àwọn onímọ̀ èdè Yorùbá pé, ọ̀pọ̀ àwọn ògo wẹẹrẹ wa ni kò leè sọ tàbí kọ èdè Yorùbá sílẹ̀.

Arábìnrin Okedeyi Ọlajumọkẹ àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Bisoye Ẹlẹṣin ní, èdè Yorùbá ní ìtumọ̀ ju èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ, táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìró rẹ̀, ohùn àti àkànlò èdè.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọ́n ní ọwọ́ àwọn òbí ni akùdé tó ń bá èdè Yorùbá ti wa, torí ọ̀pọ̀ wọn rí Yorùbá bíi èdè tí kò wúlò, tí wọn kò sì mọ̀ pé oríṣun ọrọ̀ ni èdè yìí, fún àwọn ọmọ wọn lọ̀jọ̀ ọ̀la.

Wọ́n wá gba àwọn òbí àti ìjọba nímọ̀ràn láti ṣe àgbéga èdè abínibí wa, kó má baà lọ sí òkun ìgbàgbé.