Nigeria 2019 Election: Àgbà Yorùbá ní Ila Ọrangun pèpàdé àlàáfíà

Awọn ọlọpa to n sare lọ

Oríṣun àwòrán, @deeplookers

Ọga ọlọpa to n mojuto ẹkun Kọkanla, ninu eyi ta ti ri ipinlẹ Ọyọ, Ọsun ati Ondo, Ọgbẹni Adelẹyẹ Oyebade, ti sọọ di mimọ pe gbogbo eto ti to, lati ri daju pe idibo gbogbo-gboo to n bọ lọna kẹsẹjari laisi wahala tabi kọnu-n-kọhọ kankan.

Oyebade kede ọrọ yii, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ lori abọ iwadi awọn osisẹ eleto aabo lori eto idibo to n bọ naa.

O salaye pe, awọn ọga agba ati ipẹẹrẹ ọlọpa ti mura tan lati sisẹ takuntakun ki eto idibo naa lee rọ nirọwọ-rọsẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo fikun pe, aabo to peye yoo wa fawọn ohun eelo idibo, ko ma baa bọ sibi ti kotọ.

Nigba to n sekilọ fawọn eeyan to lee maa gbero lati da wahala silẹ lasiko eto idibo naa, ọga agba ọlọpa naa wa fewe ọmọ mọ awọn janduku ẹda leti.

O kilọ fawọn tọọgi oloselu ti wọn n da omi alaafia ilu ru nilu Ila Ọrangun, Igangan, Ilesa ati kaakiri ipinlẹ Ọsun pe, yoo dara ki wọn so ewe gbejẹ mọwọ lasiko ibo naa, tori awọn ọlọpa ko ni gba igbakugba lasiko ibo naa.

Àkọlé fídíò,

Àyájọ́ èdè abínibí: Onímọ̀ ní èdè Yorùbá kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, ó rẹwà

Wayi o, ni imura silẹ fun idibo aarẹ ti yoo waye lọjọ abamẹta, agbẹnusọ fun Igbimọ awon agbagba ilu ila Ọrangun, Gabriel Ajiboye ti sọ yayayanya pe, ki gbogbo awon egbe oselu ati oludije won gba alafia laaye ninu gbogbo idibo ti yoo waye.Ajiboye so di mimo pe, ipade e jeki alafia joba yii ni o je ẹkẹta iru re, awon meji akoko ti awon se yori si rere.

Agbenuso fun Igbimo awon agbagba ni Ila naa wa bu enu ate nu ikolukogba ati iro ibon ti o waye ni awon agbegbe kan ni Ipinle Osun, to bee ge ti okan awon ara Ilu ko fi bale rara.

O wa rawo ẹbẹ si ọga agba ọlọpaa ni Naijiria lati fun won ni aabo to peye, ko si se ikilo fun awon babasale fawon oloselu ni awon ijoba ibile bii Boluwaduro, Ifedayo ati Ila Orangun.

O ni eyi ni yoo jẹ ki won lee yago fun iwa jagidijagan, paapa julo lasiko idibo, ki awon oludibo le raye se ẹtọ won laisi idiwọ.