Ìpànìyàn: Agbébọn pa 16 ní Benue, jàǹdùkú 59 kú ní Zamfara

Awọn maalu ati Fulani darandaran

Oríṣun àwòrán, @WetinNaija

Awọn agbẹbọn ti wọn funra si pe o jẹ Fulani darandaran, ti ṣe ikọlu si agbegbe Agatu kan ni Ipinlẹ Benue, níbi tí wọ́n ti pa ènìyàn mẹ́rìndínlógún.

Bẹẹ naa ni awọn janduku to ṣe ikọlu si ilu Dan Jibga ni ijọba ibilẹ Tsafe ni Zamfara ri iku he, nigba ti awọn ara ilu naa pa mọkandinlọgọta lara wọn.

Iroyin fi han pe, ni bii agogo kan oru ni awọn darandaran ṣe ikọlu naa ni abule Agatu, ti wọn n pe ni Ebete ni Ipinlẹ Benue.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi wọn ṣe n yinbọn pà awọn eniyan, ni wọn dana sun ile wọn.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Catherin Anene sọ fun awọn akọroyin wipe, iwadii n lọ lọwọ lori ikọlu naa.

Ni Zamfara, a gbọ pe awọn janduku bi ọgọsan lo ya bo ilu Dan Jibga, ti wọn si pa eniyan meje.

Àkọlé fídíò,

Àyájọ́ èdè abínibí: Onímọ̀ ní èdè Yorùbá kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, ó rẹwà

Ni kia ni a gbọ pe, awọn ara ilu naa mu awọn mọkandinlọgọta lara awọn janduku naa, ti wọn si pa wọn.

Ija naa lọ fun bii wakati mẹrin, ki awọn agbofinro to de ilu naa.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmọogun Naijirai, Clement Abiade ni awọn ti n gbiyanju lati ṣe iwadii lori bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ.