Nigeria 2019 Elections: Atiku ní káwọn olùdìbò lo káádì ìbò wọn fi yọ ààrẹ òní, ba ṣe yọ tàná

Oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP Alhaji Atiku Abubakar

Oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Atiku Abubakar, ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ ni ori Twitter ati Facebook ní Ọjọbọ, nibi to ti rọ wọn pe ki wọn jade lọ dibo lọjọ Abamẹta.

Atiku ni, ori oun wu nigba ti awọn ọmọ Naijiria fi kaadi idibo wọn yọ aarẹ ana, lasiko idibo to waye ni ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2015.

O ni, "Awa eniyan Naijiria lọ si ibi idibo pẹlu kaadi idibo wa nikan, a si yọ olori orilẹede yii nigba naa. Oun to jẹ ki ori mi wu niyẹn gẹgẹbii ọmọ Naijiria. Ni ọsẹ yii, a o ni anfani lati ṣe bẹẹ lẹẹkan si."

Atiku tẹsiwaju, o ni eni yowu ti awọn ọmọ Naijiria ba fẹ dibo fun, ki wọn gbiyanju lati jade dibo lọjọ Abamẹta.

O ni ni ọjọ idibo, ibo kan ko lagbara ju omiran lọ.

O sọ wipe, "Ẹni ti ko ba dibo, o fẹ ki ọdun mẹrin to n bọ ri bi ọdun mẹrin to lọ niyẹn. Agbara lati ri pe Naijiria bọ pada sipo, o wa ni ọwọ rẹ."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

APC ní Atiku parọ́ lórí ẹ̀sùn pé yóò jẹ́ kí ẹ̀rọ káádì ṣe aṣemáṣe