Yemi Osinbajo: Igbákejì ààrẹ ní ìṣẹ́ àti òsí tí Covid-19 kó bá wa, kò ṣe dúró wò

Yemi Osinbajo dori kodo

Oríṣun àwòrán, Others

Yoruba ni oye ni agba n wo, bẹẹ si ni agba ti ko ba kẹhun sọrọ, afaimọ ko ma kẹtan sare.

Boya eyi lo mu ki igbakeji aarẹ nilẹ wa, Yemi Osinbajo fi n lọgun nipa isẹ ati osi to n bawọn ọmọ Naijiria mulẹ, bii ẹgbẹ isu.

Osinbajo ni ipa nla ti arun Coronavirus nni lori ọrọ aje ati igbayegbadun wa ni Naijiria lojoojumọ lagbara pupọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade kan ti akọwe eto iroyin rẹ, Laolu Akande fisiti lo ti jẹyọ pe Osinbajo ke gbajare yii nibi agbeyẹwo isẹ iriju ọdun kinni awọn to dipo ilu mu.

Àkọlé fídíò,

Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

Osinbajo wa kesi awọn minisita lati gbe igbesẹ ni kanmọ n kia lori owo triliọnu meji o le diẹ naira tijọba gbe kalẹ lati mu adinku ba ipa arun naa lori ọrọ aje Naijiria.

Osinbajo ni "ọjọ kẹtadinladọrin ree ta ti se ifilọlẹ eto naa, idi si ree ta fi gbọdọ se amusẹ rẹ ni kiakia, ki ori to ta araalu jinna.

Bakan naa si la gbọdọ ri daju pe a n se odiwọn awọn aseyọri wa lojoojumọ, ta si n se gbogbo ohun to yẹ ni sise.

Akoko kii se ọrẹ wa mọ, isẹ ati osi si n jinlẹ laarin ilu si lojoojumọ ni."

Oríṣun àwòrán, Others

Nigba to n sọrọ lori eto ọgbin ọlọpọ eniyan, Osinbajo ni ijọba ti se akọsilẹ miliọnu mẹrin agbẹ lati kopa ninu rẹ.

Lori eto ilegbe, o ni ijọba yoo kọ ilegbe ẹgbẹrun lọna ọọdunrun jake jado Naijiria eyi towo rẹ ko ni ju miliọnu meji naira lọ.

O fikun pe, gbogbo awọn igbesẹ naa lo wa lati pese isẹ oojọ fun araalu.

Mi ò kọ̀wé fipò sílẹ́ - Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Profosinbajo/Instagram

Igbakeji Ààrẹ Yemi Osinbajo ti fesi si ahesọ ọrọ kan n to tan kalẹ lori ayelujara wipe, o ti binu kọwe fipo sile.

Ọsinbajo sọ lori itakun Twitter rẹ wipe, iroyin ofege ti wọpọ ni orilẹede Nigeria nitori oṣelu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "Mi o ti i kọwe fipo silẹ o. Mo duro digbi lati siṣẹ sin awọn ọmọ Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari.

A gbọ wipe awọn iroyin ofege naa sọ wipe, Osinbajo ti fi ibinu kọwe fipo silẹ nitori wipe wọn ko pe e si ibi ipade kan ni ile ijọba.