Nigeria 2019 Election: Ọjọ́ Sátidé tí wọ́n sún ìbò ààrẹ sí ni ìgbéyàwo àwọn ìbejì yìí

Nigeria 2019 Election: Ọjọ́ Sátidé tí wọ́n sún ìbò ààrẹ sí ni ìgbéyàwo àwọn ìbejì yìí

Ọjọ ayọ ni ọjọ igbeyawo jẹ fun ẹnikẹni papaa julọ laarin awọn Yoruba.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹ fun awọn ibeji yii Taiwo ati Kẹhinde Fagbọlagun lẹyin ti ọjọ igbeyawo fori sọ ọjọ ti ajọ eleto idibo INEC sun ibo aarẹ ati ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja si, eyi ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii.

Taiwo ati Kẹhinde ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ awọn ko tilẹ mọ odo t'awọn fẹ da orunla si bayii, nitori awọn ko tilẹ pe ajọ INEC yoo sun eto idibo ti o yẹ ko waye tẹlẹ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji siwaju rara.

Wọn rọ ijọba wi pe ki bẹẹ ni wọn ko maa jẹ bẹ nitori awọn ni awọn ara ilu n wo fi ṣe awokọṣe.