Nigeria 2019 Election: Ààrẹ Buhari ní k'áwọn ọmọ Nàìjíríà dìbò yan ẹni tó wù wọ́n

Muhammadu Buahri Image copyright NTA
Àkọlé àwòrán Aarẹ Muhammadu sọrọ lori idibo ọjọ Satide

Aarẹ Muhammmadu Buhari ni idibo aarẹ ati tile igbimọ aṣofin agba ọjọ Satide yoo lọ n'irọwọ rọsẹ, bẹẹ lo rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati jade dibo fun ẹni to ba wu wọn.

Aarẹ sọrọ yii nigba to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori ẹro amohun-maworan ti ijọba apapọ, NTA ati ile iṣẹ Radio Naijiria laarọ ọjọ Ẹti ṣaaju idibo ọjọ Abamẹta

Aarẹ Buhari awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti wa ni digbi lati daabo bo eeyan nibi ti wọn ba ti n dibo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí

Aarẹ ko si iyi to ju ki awọn eeyan dibo fun olori ti wọn fẹ ko maa dari wọn lọ gẹgẹ ọmọ orilẹede tootọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionScrabble: Yorúbà Scrabble ni àkọ́kọ́ ní èdè abínibí nílẹ̀ Afrika
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption''A ò mọ ohun tí á fẹ́ ṣe báyìí''

Aarẹ Buhari fikun ọrọ pe ajọ eleto idibo INEC ti ṣetan lati ṣagbatẹru idibo ti yoo lọ ni irọwọ rọsẹ lọjọ Abamẹta.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria 2019 Elections: Akala ní APC kò tó bẹ́ẹ̀ láti yọ ọmọ òun nípò alága

Aarẹ tun fi da awọn onwoye loju pe ko si ewu rara fun wọn, o ni aabo to peye yoo wa fun wọn lọjọ idibo.

Aarẹ Buhari bawọn ọmọ Naijiria sọrọ lọsẹ to kọja ki ajọ eleto idibo INEC to sun ibo to yẹ ko waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji siwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkala: Kọmísánà kò láṣẹ láti búra fún igbákejì mi bíi alága ìbílẹ̀