Nigeria 2019 Election: Fayoṣe ní EFCC ń wá owó Atiku bọ̀ wálé òun l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, Twitter/Peter Ayodele Fayose
EFCC tun fẹ yabo ile Fayose
Ile lapoti n joko dedi lorin ti gomina ana ipinlẹ Ekiti, Ayo Fayoṣe fi bọnu loju opo Twitter rẹ.
Fayoṣe ni oun gbọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbaanu ati iṣowo ilu kumọkumọ EFCC ti de silu Ekiti lati yabo ile oun to wa ni Afao Ekiti laarọ ọjọ Ẹti.
Fayọṣe ni oun gbọ pe owo ti oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar fi n ṣe ipolongo ni wọn wa.
Scrabble: Yorúbà Scrabble ni àkọ́kọ́ ní èdè abínibí nílẹ̀ Afrika
Gomina ana ipinlẹ Ekiti tun ṣalaye loju opo Twitter rẹ pe ko si ẹni to le dunkoko mọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti.
''A ò mọ ohun tí á fẹ́ ṣe báyìí''
Fayoṣe ni ifẹ awọn ọmọ ipinlẹ Ekiti ni yoo wa si imuṣẹ ni igbẹyin-gbẹyin.
#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí
Fayoṣe ni awọn kan ti gba idajọ wọn, bẹẹ ni ti awọm miran si n bọ lọna laipẹ.
O fikun ọrọ pe gbogbo rẹ yoo dopin lọjọ Abamẹta lẹyin ti idibo aarẹ ati tile aṣofin agba ba waye tan.
Àwọn òṣìṣẹ́ BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ìdùnnú lórí ayẹyẹ ọdún kan iléeṣẹ́ náà