Scrabble: Yorúbà Scrabble ni àkọ́kọ́ ní èdè abínibí nílẹ̀ Afrika

Scrabble: Yorúbà Scrabble ni àkọ́kọ́ ní èdè abínibí nílẹ̀ Afrika

Yooba Lingo jẹ ayò àwọn ọ̀dọ́ àti àgbàlagbà tí wọn a fi mọ̀ síi nipa èdè Yorùbá.

Arẹmu Anuoluwapọ Adeọla jẹ akẹkọọ gboye ni Fasiti ijọba apapọ to wa nilu Eko.

O ni oun ṣagbekalẹ eré ọpọlọ yii láti fihan pé kò si nkan ti a kò lè fi èdè Yoruba ṣagbekalẹ rẹ ti a ba ti ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu ifẹ ede Yoruba lọkan.Link

Omowe Bisoye Eleshin to jẹ olukọ agba ni fasiti Eko naa ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣe ọpọlọ ti Arẹmu ṣe lori Yoruba Lingo to jẹ Scrabble ede Yoruba.

O ni Arẹmu nikan kọ ni akẹkọọ to ti gbiyanju rẹ sẹyin, ṣugbọn o gboriyin fun Anuoluwapọ pe oun lo foritii dopin to fi ṣe eré ọpọlọ yii laṣe yanju.

Yooba Lingo yii ni akọkọ iru rẹ nilẹ Adulawọ lede abinibi wa.

Arẹmu ni eré ọpọlọ yii yoo jẹ ki àkóónú ọrọ àwọn ọdọ kún sii ni àká ọrọ wọn ati pé wọn yoo tun fi mọ òǹkà Yoruba siwaju sii.

Ko si nkan ti ogidi ọmọ Yoruba kò lè ṣagbekalẹ rẹ lede Yoruba nitori èdè to kún fọfọ ni ede Yoruba.