Nàìjíríà - orísun àwọn ọlọpọlọ pipe ninu iṣẹ litireṣọ

Top left: A make-up artist uses a phone's light to prepare a model following an electrical problem during the Lagos Fashion Week. Top right: Chimamanda Ngozi Adichie. Bottom left: Musician Davido. Bottom centre: Buses and shoppers in Lagos, Nigeria. Bottom righ: A BringBackOurGirls campaigner Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Orilẹ ede to n ṣan fun wara ati oyin awọn ọlọpọlọ pipe

O le ni miliọnu mẹrinlelọgọrin oludibo to forukọ silẹ fun idibo ọdun 2019.

Wo akọsilẹ awọn nkan abuda adamọ to fi Naijiria han gẹgẹ bii orilẹ-ede ilẹ̀ Adulawọ ti eto ọrọ ajé ẹ pọju.

1) Orin Takasufe Afro kíkọ lọ́nà àrà

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo ti gbe ògo orin Takasufe ti wọn n pe ni Afro Beats ga nile ati lẹyin odi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wizkid jẹ ọkan lara awọn ọdọmọde olowo to bẹrẹ orin kikọ lọmọ ọdun 11 nile ijọsin

Eyi tun pegede si ti orin oloogbe Fela Anikulapo Kuti to n kọ Afro Beat nigba aye rẹ ninu eyi to ti ṣadapọ orin alariwo ati takasufe papọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTunde Kelani; Èmi ò jẹ́ Baba Wande ní owó lórí fíímù Tolúwanilẹ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption‘Tunde Kelani yan mi jẹ lori fiimu ‘Toluwanilẹ’

Awọn èèkàn ti Ọlọrun ti gba fun ni Naijiria lẹnu orin kikọ lasiko yii kuro ni keremi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Diẹ lara wọn ni Wizkid, Davido, Tiwa Savage ati Jidenna.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDavido fi ọkọ̀ Porsche ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí fún Chioma Avril

Ipa wọn ninu orin lagbaye ti gba okùn de ibi pé ile iṣẹ olorin nlanla bii Universal Music Group ati Sony ti da ẹka ileeṣẹ wọn silẹ ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFalz: MURIC ní ọ̀rọ yí kọjá orin, wọ́n ni ó dilé ẹjọ́

Orin Davido to gbe jade lọdun 2017 jẹ orin to ta julọ ni Naijiria ri.

Awọn onkorin lasiko yii gba pé orin Afro Beats ti n nipa lori ọna iṣọwọ kọrin awọn miran ni ori ayelujara ni eyi to tun n fun Naijiria lokiki sii lagbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAyanbinrin Ara fi ilu kọ'rin ibilẹ Naijiria

Eyi lo bi ẹya orin bii Afro-pop, azonto, hiplife atawọn mii laarin awọn eniyan Ghana ati Naijiria bi apẹrẹ orin Oliver Twist ti DBanj tun ṣi oju awọn eniyan si i.

Awọn olorin Naijiria mii to tun ti di ilumọọka ni Yemi Alade, Tekno, Falz, Olamide, Simi, Mr Eazi, Mologo ati Patoranking.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObinrin lo mu mi fẹran orin kikọ - Patoranking

2) Awọn ogbontarigi òǹkọ̀wé

Orilẹ-ede Naijiria ti bi awọn onkọwe to ju onkọwe lọ lagbaye bẹrẹ lati ara Chinua Achebe to kọ iwe Things Fall Apart nibi ti wọn ti ta iwọn to le ni miliọnu ogun lati 1958 to ti tẹẹ.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Chinua Achebe onkọwe to kọja bẹẹ

Wole Soyinka na tun jẹ eekan to ti digi araba lai yọ Ben Okri, Oloogbe D O Fagunwa, Chigozie Obioma, Helon Habila, Chibundu Onuzo, Sefi Atta, JF Odunjọ, Chimamanda Adichie atawọn mii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIfọrọwanilẹnuwo pẹlu Ọjogbọn Wọle Soyinka
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyájọ́ èdè abínibí: Onímọ̀ ní èdè Yorùbá kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, ó rẹwà

3) Ojoojumọ ni awọn ọmọ Naijiria n pọ sii, ti wọn n bi sii

Opọlọpọ ọmọ ni awọn eniyan Naijiria n bi sii ni eyi ti odiwọn idagbasoek wọn ti fi di ajitannawo lagbaye.

Àkọlé àwòrán Odiwọn ọmọ ti Naijira n bi sii lọdọodun

Iwadii fihan pe to ba fi maa di ọdun 2017, Naijiria ṣeeṣe ko ti di orilẹ-ede kẹta to tobi ju lagbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHubert Ogunde ló m'órí mi yá láti di òṣèré

Eyi ni awọn ọdọ to ni agbara lati dibo tọdun 2019 yii tun fi n pariwo pe iṣẹ to wa ko to ṣe rara nitori ero ti pọ ju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBeautiful Nubia: Kò sí wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ láàgbáyé tí kò ní ọwọ́ ẹ̀sìn lábẹ́nú

Oloye Obnasanjọ Oluṣegun to ti dari NAijiria ri kilọ ọjọ iwaju ti a ko ba ṣọra lori ọna abayọ siṣoro yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionReminisce: Àwọn ọ̀dọ́ ló mọ ìtumọ̀ orin 'Problem'

4) Owó epo rọ̀bì tó yapa ni Naijiria láì sí iná ọba púpọ̀

Awọn kan tilẹ maa n sọ pe kii ṣe awọn olorin takasufe nikan la fi n mọ Naijiria yatọ bi ko ṣe ti ariwo ẹrọ amunawa kaakiri adugbo.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Aṣaraloge n fina ẹrọ ibanisọrọ ṣiṣẹ aje rẹ nigab tina ọba lọ

Opọ igba ni awọn agbegbe kan ko ni ina mọnamọna fun ọpọlọpọ ọ̀sẹ̀ ni eyi ti onikaluku fi ma n wa ọna abayọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọmọ Yorùbá àtàtà: Báwo lẹ se gbọ́ òwe sí ?

Bẹẹ, Naijiria ni orilẹ-ede to n pese epo rọbi julọ lagbaye ninu orilẹ-ede ilẹ Afrika. O le ni miliọnu meji àgbá epo rọbi ti wọn n pese lojumọ.Banki agbayẹ pẹsẹ iranwọ fun Naijiria

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDJ Spinall: Orin tí kò ní ìtumọ̀ ni ayé ń tẹ́wẹ́gbà

Owó ti wọn n ri n ninu epo rọbi pọ nitootọ ṣugbọn iṣoro ina ọba ṣi n gbẹbọ lọwọ wọn.

5) Naijiria- Ilé Boko Haram alakatakiti ẹsin Islam

Awọn alakatakiti ẹsin Islam lo bẹrẹ ogun Boko Haram ni apa ariwa iwọ oorun Naijiria ni eyi ti o ti gba ọpọ ẹmi ati dukia.

Orọ ogun yii lo bi ipede bring bag our girls lori ayelujara ti awọn ajajangbara kan ṣe n beere fun awọn ọmọdebinrin Chibok ti Boko Haram ji gbe lọ.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán O ṣi ku ọmọdebinrin Chibok 112 ti ijọba ṣi n wa

Odun 2002 ni wọn ni wọn da Boko Haram silẹ ni agbegbe Maiduguri nipinlẹ Borno.

Orukọ won tumọ si pe eewọ ni imọ ẹkọ ọlaju iwe ni eyi ti ijọba Naijiria ṣi n wa ojutu sii titi di asiko yii.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Opo igba ni Boko Haram ti fi fọnran sita pé awọn ti bori ọmọ ogun Naijiria

Ni asiko kan ni awọn ọmọ ogun olotẹ yii gba ijọba agbegbe kan ni ila oorun ariwa Naijiria pẹlu ofin Sheria ki ijọba Naijiria to gab wọn pada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBoko Haram yóò dá Leah sílé

Bayii, omodebinrin Leah Sharibu, akẹkọọ ile iwe Dapchi kan lo ku ti ijọba ko tii ri gba ninu awọn omodebinrin mii ti wọn tun jigbe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFemi Falana: kò yé kí ìdájọ́ òfin yàtó síra wọn ni Naijiria
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀