Lassa Fever:Ondo, Oyo, Kwara wà lára ìpínlẹ̀ tó kásáa ibà Lassa

Ekute n jẹ koriko
Àkọlé àwòrán,

Arun lassa ni Naijiria

Ibùdó tó ń kojú àwọn àìsàn tó bá súyọ ní Nàìjíríà ní láàrin ọjọ́ kọkànlá sí ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdun 2019, àkọsílẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ló ti wà nípa ibà Lassa lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Oludari ibudo yii, Chike Ihekweazu sọ eyi di mimọ pe afikun iṣẹlẹ mẹẹdọgbọ́n yii ti sọ gbogbo rẹ laarin oṣu kinni si isisiyii di ọọdunrun o le marun le laadọta ni ipinlẹ mọkandinlogun to fi mọ olu ilu orilẹede yii.

O ni o ti to eniyan marunlelaadọrin to ti gbẹmi mi latari iba Lassa lati igba to ti bẹrẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ ọ, ni bayii, ipinlẹ Edo, Ondo, Bauchi, Nasarawa, Ebonyi, Plateau, Taraba, Adamawa, Gombe, Kaduna, Kwara, Benue, Rivers, Kogi, Enugu, Imo, Delta, Oyo ati Kebbi to fi mọ ilu Abuja ni kọọkan lo ti ni akọsilẹ iṣẹlẹ iba Lassa.

O j ko di mimọ pe, oṣiṣẹ eleto ilera kan naa tun ti fara ko o ni ipinlẹ Edo eyi to sọ ọ di mtala oṣiṣẹ eleto ilera to ti fara gba a lati igba to bẹ silẹ.