2019 elections: INEC ní kò sáyè fún màjèṣín láti dìbò

Ọjọgbọn Mahmood Yakubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

INEC ni iwa irufin ni fun majeṣin lati dibo lorilẹede Naijiria.

Ajọ INEC ti ṣalaye pe oun ko ni fi oju rere wo ọmọde ti ọjọ ori rẹ ko tii to dibo yoowu ti ọwọ ba tẹ ni ibudo idibo.

Alaga ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ṣalaye yii ni ọjọ ẹti lasiko to fi n ba awọn alẹnulọrọ ninu eto idibo lorilẹede Naijiria sọrọ nilu Abuja lori igbaradi fun idibo aarẹ atawọn aṣofin apapọ ti yoo waye lọjọ abamẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọgbọn Yakubu ni iwa irufin ni fun majeṣin lati dibo lorilẹede Naijiria.

O ni ajọ INEC ati ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria yoo ṣiṣẹ pọ lati rii pe gbogbo awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko tii to dibo ni wọn fi panpẹ ofin mu.

Àkọlé fídíò,

Ẹ wo oun tí ìbejì yìí ṣe nítorí ìgbéyàwó wọn bọ́ sí ọjọ́ ìdìbò ààrẹ

"Awọn ọmọ Naijiria ti ọjọ ori wọn jẹ ọdun mejidinlogun tabi ju bẹẹ lọ lo lẹtọ ati dibo. Iwa ti ko ba ofin mu ni fun ẹnikẹni ti ọjọ ori rẹ kere si eyi lati dibo. Nitori naa mo fi asiko yii jawe ikilọ ranṣẹ sawọn to ba fẹ ṣe agbodegba fawọn majeṣin bẹẹ pe ọwọ ofin yoo ba wọn."

Iroyin okiki awọn majeṣin to n dibo gba ile kan lasiko idibo apapọ ọdun 2015. Yatọ si eyi, ajọ INEC ti ke gbajare lori bi awọn majesin ṣe tun forukọ silẹ lati dibo lasiko iforukọsilẹ oludibo to waye lọdun 2018.